Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 58

Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu.

58 Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòótọ́
    ẹ̀yin ìjọ ènìyàn?
Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́
    ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?
Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìṣòdodo,
    ọwọ́ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.

Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà,
    lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké.
Oró wọn dàbí oró ejò,
    wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,
tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú,
    bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.

Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run;
    ní ẹnu wọn,
ká ọ̀gàn àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.
Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń sàn lọ;
    nígbà tí ó bá fa ọfà rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.
Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé
    bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn.

Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún;
    bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.
10 Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn,
    nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.
11 Àwọn ènìyàn yóò wí pé,
    “Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo;
    lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”

Jeremiah 3:15-25

15 Lẹ́yìn èyí, èmi ó fún ọ ní àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti inú ọkàn mi, tí wọn yóò ṣáájú yín pẹ̀lú òye àti ìmọ̀. 16 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí ẹ̀yin bá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí, “àwọn ènìyàn kò tún lè sọ pé, ‘Àpótí ẹ̀rí Olúwa’ kò ní wá sí ìrántí wọn mọ́, a kì yóò pàdánù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sì tún kan òmíràn mọ́. 17 Ní ìgbà náà, wọn yóò pe Jerusalẹmu ní ìtẹ́ Olúwa gbogbo orílẹ̀-èdè yóò péjọ sí Jerusalẹmu láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ Olúwa, wọn kì yóò sì tún tẹ̀lé àyà líle búburú wọn mọ́. 18 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ni ilé Juda yóò darapọ̀ mọ́ ilé Israẹli. Wọn yóò sì wá láti ilẹ̀ àríwá wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní.

19 “Èmi fúnra mi sọ wí pé,

“ ‘Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó, kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrin
    kí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó.’
Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní ‘Baba mi’
    o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn.
20 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí aláìgbàgbọ́ obìnrin sí ọkọ rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ o jẹ́ aláìgbàgbọ́ sí mi.
Ìwọ ilé Israẹli”
    ni Olúwa wí.

21 A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga,
    ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli,
nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po,
    wọ́n sì ti gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn.

22 “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,
    Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn.”

“Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹ
    nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run wa.
23 Nítòótọ́, asán ni ìbọ̀rìṣà àti ìrúkèrúdò tí ó wà ní àwọn orí òkè
    kéékèèkéé àti àwọn òkè gíga;
Nítòótọ́, nínú Olúwa Ọlọ́run
    wa ni ìgbàlà Israẹli wà.
24 Láti ìgbà èwe wa ni àwọn òrìṣà ìtìjú ti
    jẹ èso iṣẹ́ àwọn baba wa run,
ọ̀wọ́ ẹran wọn àti agbo ẹran wọn,
    ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.
25 Jẹ́ kí a dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa,
    kí ìtìjú wa bò wá mọ́lẹ̀.
A ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa,
    àwa àti àwọn baba wa,
láti ìgbà èwe wa títí di òní
    a kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.”

Luku 14:15-24

Òwe nípa àsè ńlá

15 (A)Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jókòó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó wí fún Jesu pé, “Alábùkún ni fún ẹni tí yóò jẹ oúnjẹ àsè ní ìjọba Ọlọ́run!”

16 (B)Jesu dá a lóhùn pé, “Ọkùnrin kan ṣe àsè alẹ́ ńlá, ó sì pe ènìyàn púpọ̀. 17 Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Ẹ wá; nítorí ohun gbogbo ṣetán!’

18 “Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí ohun kan. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’

19 “Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra àjàgà màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’

20 (C)“Ẹ̀kẹta sì wí pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.’

21 (D)“Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpópó ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúnkùn ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí.’

22 “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, ‘Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, ààyè sì ń bẹ síbẹ̀.’

23 “Olúwa náà sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà pé, ‘Jáde lọ sí òpópó, àti sí ọ̀nà ọgbà, kí o sì rọ̀ wọ́n láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún. 24 Nítorí mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a ti pè, kì yóò tọ́wò nínú àsè ńlá mi!’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.