Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
99 Olúwa jẹ ọba;
jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì
Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù
jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.
2 Olúwa tóbi ní Sioni;
Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ.
3 Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi
tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni òun.
4 Ọba ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo,
ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀;
ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu.
5 Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa
ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.
6 Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀
Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀
wọ́n ké pe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.
7 Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀,
wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.
8 Olúwa Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn;
ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì àwọn ọmọ Israẹli
ìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedéédéé wọn jẹ wọ́n
9 Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa
kí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀
nítorí Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.
6 Ṣùgbọ́n kí ó yé yín pé kì í ṣe nítorí òdodo yín ni Olúwa Ọlọ́run yín fi ń fún un yín ní ilẹ̀ rere náà, láti ní, nítorí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ jẹ́.
Ère òrìṣà wúrà
7 Ẹ rántí, ẹ má sì ṣe gbàgbé bí ẹ̀yin ti mú Olúwa Ọlọ́run yín bínú ní aginjù. Láti ọjọ́ ti ẹ tí kúrò ní Ejibiti ni ẹ̀yin ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa títí tí ẹ̀yin fi dé ìhín yìí. 8 (A)Ní Horebu ẹ̀yin ti mú kí Olúwa bínú, títí dé bi pé ó fẹ́ run yín. 9 Nígbà tí mo gòkè lọ láti lọ gba wàláà òkúta, wàláà májẹ̀mú ti Olúwa ti bá a yín dá. Ogójì ọ̀sán àti òru ni mo fi wà lórí òkè náà, èmi kò fẹnu kan oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni ń kò mu omi. 10 Olúwa fún mi ní wàláà òkúta méjì tí a fi ìka Ọlọ́run kọ. Lórí wọn ni a kọ àwọn òfin tí Ọlọ́run sọ fún un yín lórí òkè láàrín iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀ sí.
11 Lópin ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí, Olúwa fún mi ní sílétì òkúta méjì, wàláà òkúta májẹ̀mú náà. 12 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sọ fún mi pé, “Sọ̀kalẹ̀ kúrò níhìn-ín kíákíá, torí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde láti Ejibiti ti hùwà ìbàjẹ́. Wọ́n ti yípadà kúrò, nínú ọ̀nà mi, wọ́n sì ti ṣe ère dídá fún ara wọn.”
13 Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle gbá à ni wọ́n. 14 Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n run wọ́n, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè tí ó lágbára tí ó sì pọ̀jù wọ́n lọ.”
Àwọn ìpè Korneliu fún Peteru
10 (A)Ọkùnrin kan sì wà ni Kesarea ti a ń pè ní Korneliu, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Itali. 2 Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo. 3 Níwọ́n wákàtí kẹsànán ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere angẹli Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Korneliu!”
4 Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kín ni, Olúwa?”
Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run fún ìrántí. 5 Sì rán ènìyàn nísinsin yìí lọ sí Joppa, kí wọn sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru. 6 Ó wọ̀ sí ilé Simoni aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí Òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.”
7 Nígbà tí angẹli náà tí ó bá Korneliu sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, àti ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo. 8 Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Joppa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.