Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé
89 Ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa, títí láé ni;
ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run
90 Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran;
ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.
91 Òfin rẹ dúró di òní
nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.
92 Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,
èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.
93 Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé,
nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́
94 Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ
èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.
95 Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run,
ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.
96 Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin;
ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.
27 Lẹ́yìn tí ọba fi ìwé kíká náà tí ọ̀rọ̀ tí Baruku kọ láti ẹnu Jeremiah jóná tán, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá: 28 “Wí pé, tún mú ìwé kíká mìíràn kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé kíká èkínní tí Jehoiakimu ọba Juda fi jóná. 29 Kí o sì wí fún Jehoiakimu ọba Juda pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ìwọ ti fi ìwé kíká náà jóná, o sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀wé sínú rẹ̀, pé lóòtítọ́ ni ọba Babeli yóò wá, yóò sì pa ilẹ̀ run, àti ènìyàn, àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀.” 30 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí ní ti Jehoiakimu ọba Juda pé: Òun kì yóò ní ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, à ó sì sọ òkú rẹ̀ nù fún ooru ní ọ̀sán àti fún òtútù ní òru. 31 Èmi ó sì jẹ òun àti irú-ọmọ rẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìyà nítorí àìṣedéédéé wọn; èmi ó sì mú gbogbo ibi tí èmi ti sọ sí wọn wá sórí wọn, àti sórí àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn Juda, nítorí tí wọn kò fetísí mi.’ ”
32 Nígbà náà ni Jeremiah mú ìwé kíká mìíràn fún Baruku akọ̀wé ọmọ Neriah, ẹni tí ó kọ̀wé sínú rẹ̀ láti ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé tí Jehoiakimu ọba Juda ti sun níná. A sì fi onírúurú ọ̀rọ̀ bí irú èyí kún pẹ̀lú.
Jesu wo ọ̀pọ̀ ènìyàn sàn
38 (A)Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú Sinagọgu, ó sì wọ̀ ilé Simoni lọ; ibà sì ti dá ìyá ìyàwó Simoni dùbúlẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀. 39 Ó sì súnmọ́ ọ, ó bá ibà náà wí; ibà sì náà sì fi sílẹ̀. O sì dìde lọ́gán, ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
40 Nígbà tí oòrùn sì ń wọ̀, àwọn ènìyàn gbe àwọn aláìsàn, tó ní onírúurú àìsàn wá sọ́dọ̀ Jesu; ó sì fi ọwọ́ lé olúkúlùkù wọn, ó sì mú wọn láradá. 41 Àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde lára ẹni púpọ̀ pẹ̀lú, wọ́n ń kígbe, wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run!” Ó sì ń bá wọn wí kò sì jẹ́ kí wọn kí ó fọhùn: nítorí tí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi náà.
42 (B)Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Jesu sì jáde lọ, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀. Ìjọ ènìyàn sì ń wá a kiri, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì dá a dúró, nítorí kí ó má ba à lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn. 43 Ṣùgbọ́n ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò lè ṣàìmá wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú mìíràn pẹ̀lú: nítorí náà ni a sá ṣe rán mi.” 44 (C)Ó sì ń wàásù nínú Sinagọgu ti Judea.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.