Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 145

Saamu ìyìn. Ti Dafidi.

145 Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;
    Èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé
Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́
    èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé.

Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:
    kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.
Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn;
    wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ
Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo,
    èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ.
Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù
    èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀.
Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀
    ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ.

Olóore-ọ̀fẹ́ ni Olúwa àti aláàánú
    ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.

Olúwa dára sí ẹni gbogbo;
    ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá.
10 Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni
    yóò máa yìn ọ́ Olúwa;
    àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ.
11 Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ
    wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ,
12 Kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀
    àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo.
13 Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni,
    àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.
14 Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró
    ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.
15 Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,
    ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ
16 Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ
    ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.

17 Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
    àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.
18 Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,
    sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.
19 Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ;
    ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.
20 Olúwa dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí
    ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni
    búburú ní yóò parun.

21 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa.
    Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.

Orin Solomoni 4:1-8

Olùfẹ́

Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olólùfẹ́ mi!
    Háà, ìwọ jẹ́ arẹwà!
    Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ
irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́.
    Tí ó sọ̀kalẹ̀ lórí òkè Gileadi.
Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò
    tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀;
olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́;
    kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró.
Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó;
    ẹnu rẹ̀ dùn.
Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pomegiranate
    lábẹ́ ìbòjú rẹ
Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi,
    tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra;
lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún àpáta kọ́,
    gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.
Ọmú rẹ̀ méjèèjì dàbí abo egbin méjì
    tí wọ́n jẹ́ ìbejì
    tí ń jẹ láàrín ìtànná ewéko lílì.
Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀
    tí òjìji yóò fi fò lọ,
Èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá
    àti sí òkè kékeré tùràrí.
Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi;
    kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ.

Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi,
    ki a lọ kúrò ní Lebanoni.
Àwa wò láti orí òkè Amana,
    láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni,
láti ibi ihò àwọn kìnnìún,
    láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn.

1 Kọrinti 1:3-17

(A)Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jesu Kristi.

Ìdúpẹ́

(B)Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kristi Jesu. Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ yín gbogbo àti nínú ìmọ̀ yín gbogbo. Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kristi ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín. Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyìí ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi. (C)Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jesu Kristi. (D)Ọlọ́run, nípasẹ̀ ẹni ti a pè yín sínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, jẹ́ Olóòtítọ́.

Ìyapa nínú ìjọ Ọlọ́run

10 Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi, pé kí gbogbo yín fohùn ṣọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyapa láàrín yín, àti pé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà. 11 Ẹ̀yin ará mi, àwọn kan láti ilé Kloe sọ di mí mọ̀ fún mi pé ìjà ń bẹ́ láàrín yín. 12 (E)Ohun tí mo ń sọ ní pé: Olúkúlùkù yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Paulu”; “Èmi tẹ̀lé Apollo” òmíràn wí pé “Èmi tẹ̀lé Kefa, Peteru”; àti ẹlòmíràn wí pé “Èmi tẹ̀lé Kristi.”

13 (F)Ǹjẹ́ a ha pín Kristi bí? Ṣé a kan Paulu mọ́ àgbélébùú fún un yín bí? Ǹjẹ́ a tẹ̀ yín bọ omi ní orúkọ Paulu bí? 14 (G)Inú mi dún púpọ̀ pé èmi kò tẹ ẹnikẹ́ni nínú yín bọ omi yàtọ̀ sí Krisipu àti Gaiu. 15 Nítorí náà kò sí ẹni tí ó lè sọ pé òun ṣe ìtẹ̀bọmi ní orúkọ èmi fúnra ara mi. 16 (H)(Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún tẹ ìdílé Stefana bọ omi; lẹ́yìn èyí, èmí kò rántí pé mo tẹ ẹnikẹ́ni bọ omi mọ́ níbikíbi). 17 (I)Nítorí Kristi kò rán mi láti máa ṣe ìtẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n ó rán mi láti máa wàásù ìhìnrere: kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn, kí a máa ṣe sọ àgbélébùú Kristi dí aláìlágbára.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.