Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run,
òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.
6 Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,
àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá;
ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.
7 Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run!
Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.
8 Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi;
ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.
9 Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà:
nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.
10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n
àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!
3 “Bí ọkùnrin kan bá sì kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀
tí obìnrin náà sì lọ fẹ́ ọkọ mìíràn,
ǹjẹ́ ọkùnrin náà tún lè tọ̀ ọ́ wá?
Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kò ní di aláìmọ́ bí?
Ṣùgbọ́n ìwọ ti gbé pẹ̀lú onírúurú panṣágà gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́,
ṣé ìwọ yóò tún padà sọ́dọ̀ mi bí?”
ni Olúwa wí.
2 “Gbé ojú rẹ sókè sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì,
kí o sì wò ó ibi kan ha wà tí a kò bà ọ́ jẹ́?
Ní ojú ọ̀nà, ìwọ jókòó de àwọn olólùfẹ́,
bí i ará Arabia kan nínú aginjù,
ìwọ sì ti ba ilẹ̀ náà jẹ́
pẹ̀lú ìwà àgbèrè àti ìwà búburú rẹ.
3 Nítorí náà, a ti fa ọ̀wààrà òjò sẹ́yìn,
kò sì ṣí òjò àrọ̀kúrò.
Síbẹ̀ ìwọ ní ojú líle ti panṣágà,
ìwọ sì kọ̀ láti ní ìtìjú.
4 Ǹjẹ́ ìwọ kò ha a pè mí láìpẹ́ yìí pé,
‘Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.
5 Ìwọ yóò ha máa bínú títí?
Ìbínú rẹ yóò ha máa lọ títí láé?’
Báyìí ni o ṣe ń sọ̀rọ̀
ìwọ ṣe gbogbo ibi tí ìwọ le ṣe.”
18 Nígbà tí Simoni rí i pé nípa gbígbé ọwọ́ lé ni ni a ń ti ọwọ́ àwọn aposteli fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n, 19 ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”
20 Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run! 21 Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déédé níwájú Ọlọ́run. 22 Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búburú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dárí ète ọkàn rẹ jì ọ́. 23 (A)Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹró ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀.”
24 Nígbà náà ni Simoni dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.