Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Olùgbàlà Israẹli kan ṣoṣo
43 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí
ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu
ẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Israẹli:
“Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;
Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.
2 Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,
Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;
àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá
wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.
Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,
kò ní jó ọ;
ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
3 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ;
Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ,
Kuṣi àti Seba dípò rẹ.
4 Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,
àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,
Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,
àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ.
5 Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;
Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá
èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn.
6 Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’
Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’
Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá
àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—
7 ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́,
tí mo dá fún ògo mi,
tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”
Saamu ti Dafidi.
29 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
Ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.
2 Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;
sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.
3 Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;
Ọlọ́run ògo sán àrá,
Olúwa san ara.
4 Ohùn Olúwa ní agbára;
ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
5 Ohùn Olúwa fa igi kedari;
Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.
6 Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,
àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.
7 Ohùn Olúwa ń ya
bí ọwọ́ iná mọ̀nà
8 Ohùn Olúwa ń mi aginjù.
Olúwa mi aginjù Kadeṣi.
9 Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,
ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.
Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”
10 Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;
Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.
11 Kí Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;
bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.
14 Nígbà tí àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu sí gbọ́ pé àwọn ara Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Peteru àti Johanu sí wọn. 15 Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́: 16 nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bà lé ẹnikẹ́ni nínú wọn; kìkì pè a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa ni. 17 Nígbà náà ni Peteru àti Johanu gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́.
15 (A)Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Johanu, bí òun ni Kristi tàbí òun kọ́; 16 (B)Johanu dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamitiisi yín; ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú: òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín: 17 Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tó tó, kí ó sì kó alikama rẹ̀ sínú àká; ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”
Ìtẹ̀bọmi àti ìtàn ìdílé Jesu
21 (A)(B) Nígbà tí a ṣe ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamitiisi Jesu pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀, 22 (C)Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.