Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Orin Maria
46 Maria sì dáhùn, ó ní:
“Ọkàn mi yin Olúwa lógo,
47 Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
48 Nítorí tí ó ṣíjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀
ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀: Sá wò ó.
Láti ìsinsin yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
49 Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi;
Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.
50 Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀
láti ìrandíran.
51 Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀;
o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.
52 Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn,
o sì gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ lékè.
53 Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebi ń pa
ó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.
54 Ó ti ran Israẹli ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́,
Ní ìrántí àánú rẹ̀;
55 (A)sí Abrahamu àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa,
àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”
Òkè Olúwa
4 (A)Ní ọjọ́ ìkẹyìn
a ó fi òkè ilé Olúwa lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá,
a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ,
àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀.
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá,
wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa,
àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu
Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,
kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.”
Òfin yóò jáde láti Sioni wá,
àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.
3 Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,
yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré.
Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀
àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé
orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.
4 (B)Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀
àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀,
ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n,
nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ̀rọ̀.
5 Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn,
olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀,
ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ Olúwa.
Ọlọ́run wa láé àti láéláé.
Ọ̀kan nínú Kristi
11 Nítorí náà ẹ rántí pé, nígbà àtijọ́ rí, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ Kèfèrí nípa ti ìbí, tí àwọn tí a ń pè ní “aláìkọlà” láti ọwọ́ àwọn tí ń pe ara wọn “akọlà” (Èyí ti a fi ọwọ́ ènìyàn ṣe sí ni ni ara)— 12 (A)Ẹ rántí pé ni àkókò náà ẹ̀yin wà láìní Kristi, ẹ jẹ́ àjèjì sí Israẹli, àti àjèjì sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà, láìní ìrètí, àti láìní Ọlọ́run ni ayé. 13 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kristi Jesu ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kristi.
14 Nítorí òun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórìíra èyí tí ń bẹ láàrín yín. 15 Ó sì ti fi òpin sí ọ̀tá náà nínú ara rẹ̀, àní sí òfin àti àṣẹ wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ nínú ìlànà, kí ó lè sọ àwọn méjèèjì di ẹni tuntun kan nínú ara rẹ̀, kí ó sì ṣe ìlàjà 16 àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú; nípa èyí tí yóò fi pa ìṣọ̀tá náà run. 17 (B)Ó sì ti wá, ó sì ti wàásù àlàáfíà fún ẹ̀yin tí o jìnnà réré, àti àlàáfíà fún àwọn tí o súnmọ́ tòsí. 18 Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan.
19 Ǹjẹ́ nítorí náà ẹ̀yin kì í ṣe àlejò àti àjèjì mọ́, ṣùgbọ́n àjùmọ̀jogún ọmọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn ará ilé Ọlọ́run; 20 a sì ń gbé yín ró lórí ìpìlẹ̀ àwọn aposteli, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jesu Kristi fúnrarẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé; 21 Nínú rẹ ni gbogbo ilé náà, tí a ń kọ wà papọ̀ ṣọ̀kan tí ó sì ń dàgbàsókè láti di tẹmpili mímọ́ kan nínú Olúwa: 22 Nínú rẹ̀ ni a ń gbé ẹ̀yin pẹ̀lú ró pẹ̀lú fún ibùjókòó Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.