Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 80:1-7

Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu.

80 Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli;
    ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran;
    ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde
Níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase.
    Ru agbára rẹ̀ sókè;
wá fún ìgbàlà wa.

Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;
    jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí a bá à lè gbà wá là.

Olúwa Ọlọ́run alágbára,
    ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó
    sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?
Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn
    ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa,
    àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.

Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;
    jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,
    kí a ba à lè gbà wá là.

Isaiah 66:7-11

(A)“Kí ó tó lọ sí ìrọbí,
    ó ti bímọ;
kí ó tó di pé ìrora dé bá a,
    ó ti bí ọmọkùnrin.
Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?
    Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?
Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kan
    tàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan?
Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbí
    bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.
Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí
    kí èmi má sì mú ni bí?”
    ni Olúwa wí.
“Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ
    nígbà tí mo ń mú ìbí wá?”
    Ni Ọlọ́run yín wí.
10 “Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i,
    gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀;
ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀,
    gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.
11 Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn
    nínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára;
Ẹ̀yin yóò mu àmuyó
    ẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”

Luku 13:31-35

Jesu káàánú fún Jerusalẹmu

31 Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisi tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhìn-ín yìí: nítorí Herodu ń fẹ́ pa ọ́.”

32 (A)Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, ‘Kíyèsi i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lónìí àti lọ́la, àti ní ọjọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.’ 33 Ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ má rìn lónìí, àti lọ́la, àti ní ọ̀túnla: dájúdájú wòlíì kan ki yóò ṣègbé lẹ́yìn odi Jerusalẹmu.

34 (B)“Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́! 35 (C)Sá wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. Lóòtítọ́ ni mo sì wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi títí yóò fi di àkókò tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.