Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ẹ̀ka láti ọ̀dọ̀ Jese
11 (A)Èèkàn kan yóò sọ láti ibi
kùkùté Jese,
láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan
yóò ti so èso.
2 (B)Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e
ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye
ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára
ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa
3 Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa.
Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí,
tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,
4 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní,
pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu
fún àwọn aláìní ayé.
Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀,
pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.
5 (C)Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀
àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.
6 (D)Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé,
ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́
ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún
àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀
ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.
7 Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀,
àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀,
kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko
gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.
8 Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,
ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀.
9 Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run
ní gbogbo òkè mímọ́ mi,
nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa
gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.
8 Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn,
odi alágbára ọmọbìnrin Sioni,
a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín;
ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”
9 Kí ni ìwọ ha ń kígbe sókè sí nísinsin yìí?
Ǹjẹ́ ìwọ kò ní ọba bí?
Àwọn ìgbìmọ̀ rẹ ṣègbé bí?
Nítorí ìrora ti dì ọ́ mú bí obìnrin tí ń rọbí.
10 Máa yí síhìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora,
ìwọ obìnrin Sioni,
bí ẹni tí ń rọbí,
nítorí nísinsin yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú,
ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó.
Ìwọ yóò lọ sí Babeli;
níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà.
Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.
11 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ.
Wọ́n sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́,
Ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Sioni!”
12 Ṣùgbọ́n wọn kò mọ
èrò inú Olúwa;
Bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn,
nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà.
13 “Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Sioni,
nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin,
èmi yóò sì sọ pátákò rẹ̀ di idẹ
ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pátápátá.”
Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún Olúwa
àti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo ayé.
31 Olúwa sì wí pé, “Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé? Kí ni wọ́n sì jọ? 32 Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé:
“ ‘Àwa fọn fèrè fún yín,
ẹ̀yin kò jó àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín,
ẹ̀yin kò sọkún!’
33 (A)Nítorí Johanu Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí wáìnì; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù?’ 34 (B)Ọmọ ènìyàn dé, ó ń jẹ, ó sì ń mu; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Wò ó, ọ̀jẹun, àti ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn “ẹlẹ́ṣẹ̀!” ’ 35 Ṣùgbọ́n ọgbọ́n ni a dá láre nípasẹ̀ ọmọ rẹ.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.