Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 12:2-6

Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,
    èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.
Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,
    òun ti di ìgbàlà mi.”
Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi
    láti inú kànga ìgbàlà.

Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé:

“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,
    Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
ohun tí ó ti ṣe
    kí o sì kéde pé a ti gbé
    orúkọ rẹ̀ ga.
Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,
    jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.
Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni,
    nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo
    ti Israẹli láàrín yín.”

Amosi 9:8-15

“Dájúdájú, ojú Olúwa Olódùmarè
    ń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀.
Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀
    Síbẹ̀ Èmi kò nípa ilé Jakọbu run pátápátá,”
    ni Olúwa wí.
“Nítorí Èmi yóò pàṣẹ,
    Èmi yóò sì mi ilé Israẹli
    ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè
bí a ti ń jọ nǹkan nínú ajọ̀
    tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀.
10 Gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn mi
    ni yóò ti ipa idà kú
gbogbo àwọn ti ń wí pé,
    ‘Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́.’

Ìmúpadàbọ̀ Israẹli

11 (A)“Ní ọjọ́ náà ní
    Èmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró,
Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya,
    Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè,
    Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì,
12 kí wọn le jogún ìyókù Edomu
    àti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,”
    ni Olúwa, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí.

13 (B)“Ọjọ́ náà ń bọ,” ni Olúwa wí,

“tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá
    Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá
Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀
    Tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèkéé.
14     Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Israẹli ènìyàn mi padà bọ̀.

“Wọn yóò sì kọ́ ahoro ìlú, wọn yóò sì máa gbé inú wọn
    Wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì mu ọtí wáìnì wọn
    wọn yóò sì ṣe ọgbà pẹ̀lú, wọn yóò sì jẹ èso inú wọn
15 Èmi yóò gbin Israẹli sí orí ilẹ̀ rẹ̀.
    A kì yóò sì fà wọn tu mọ́ láéláé
    kúrò ni orí ilẹ̀ ti mo fi fún wọn,”

ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wí.

Luku 1:57-66

Ìbí Johanu onítẹ̀bọmi

57 Nígbà tí ọjọ́ Elisabeti pé tí yóò bí; ó sì bí ọmọkùnrin kan. 58 Àwọn aládùúgbò, àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ bí Olúwa ti fi àánú ńlá hàn fún un, wọ́n sì bá a yọ̀.

59 (A)Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n wá láti kọ ọmọ náà nílà; wọ́n sì fẹ́ sọ orúkọ rẹ̀ ní Sekariah, gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba rẹ̀. 60 Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Johanu ni a ó pè é.”

61 Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”

62 Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é. 63 Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn. 64 Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run. 65 Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn: a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Judea. 66 Ó sì jẹ́ ohun ìyanu fún gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì tò ó sínú ọkàn wọn, wọ́n ń wí pé, “Irú-ọmọ kín ni èyí yóò jẹ́?” Nítorí tí ọwọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.