Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Orin fún ìgòkè.
126 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,
àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
2 Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,
àti ahọ́n wa kọ orin;
nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,
Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
3 Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;
nítorí náà àwa ń yọ̀.
4 Olúwa mú ìkólọ wa padà,
bí ìṣàn omi ní gúúsù.
5 Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn
yóò fi ayọ̀ ka.
6 Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,
tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,
lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,
yóò sì ru ìtí rẹ̀.
3 (A)Fún ọwọ́ àìlera lókun,
mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun:
4 Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé
“Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù;
Ọlọ́run yín yóò wá,
òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san;
pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́
òun yóò wá láti gbà yín là.”
5 (B)Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú
àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́.
6 Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín,
àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀.
Odò yóò tú jáde nínú aginjù
àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.
7 Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà,
ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi.
Ní ibùgbé àwọn dragoni,
níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀,
ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi.
Jesu àti Johanu onítẹ̀bọmi
18 (A)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu sì sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún un. 19 Nígbà tí Johanu sì pe àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rán wọn sọ́dọ̀ Olúwa, wí pé, “ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”
20 Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, “Johanu onítẹ̀bọmi rán wa sọ́dọ̀ rẹ, pé, ‘Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?’ ”
21 (B)Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti ààrùn, àti ẹ̀mí búburú; ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú. 22 (C)Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ, ẹ ròyìn nǹkan tí ẹ̀yin rí, tí ẹ̀yin sì gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, àti fún àwọn òtòṣì ni à ń wàásù ìhìnrere. 23 Alábùkún fún sì ni ẹnikẹ́ni tí kò kọsẹ̀ lára mi.”
24 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ìjọ ènìyàn ní ti Johanu pé, “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ sí ijù lọ wò? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mì? 25 Ṣùgbọ́n kín ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ní aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́? Wò ó, àwọn tí á wọ̀ ní aṣọ ògo, tí wọ́n sì ń jayé, ń bẹ ní ààfin ọba! 26 Ṣùgbọ́n kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Wòlíì? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ! 27 (D)Èyí yìí ni ẹni tí a ti kọ̀wé nítorí rẹ̀ pé:
“ ‘Wò ó, èmi yóò rán oníṣẹ́ mi síwájú rẹ;
ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’
28 Mo wí fún yín nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí wòlíì tí ó pọ̀ ju Johanu Onítẹ̀bọmi lọ: ṣùgbọ́n ẹni tí ó kéré jùlọ ní ìjọba Ọlọ́run, ó pọ̀jù ú lọ.”
29 (E)(Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó gbọ́ àti àwọn agbowó òde, wọ́n dá Ọlọ́run láre, nítorí tí a fi ìtẹ̀bọmi Johanu tẹ̀ wọn bọ mi. 30 Ṣùgbọ́n àwọn Farisi àti àwọn amòfin kọ ète Ọlọ́run fún ara wọn, a kò bamitiisi wọn lọ́dọ̀ rẹ̀.)
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.