Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 126

Orin fún ìgòkè.

126 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,
    àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,
    àti ahọ́n wa kọ orin;
nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,
    Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;
    nítorí náà àwa ń yọ̀.

Olúwa mú ìkólọ wa padà,
    bí ìṣàn omi ní gúúsù.
Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn
    yóò fi ayọ̀ ka.
Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,
    tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,
lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,
    yóò sì ru ìtí rẹ̀.

Isaiah 40:1-11

Ìtùnú fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run

40 Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú,
    ni Ọlọ́run yín wí.
Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu
    kí o sì kéde fún un
pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí,
    pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwa
    ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

(A)Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù:
    “Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
    ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa.
(B)Gbogbo Àfonífojì ni a ó gbé sókè,
    gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀;
wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti
    ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ,
Ògo Olúwa yóò sì di mí mọ̀
    gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i.
    Nítorí ẹnu Olúwa ni ó ti sọ ọ́.”

(C)Ohùn kan wí pé, “Kígbe sókè.”
    Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?”

“Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko,
    àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná igbó.
Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,
    nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n.
    Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.
Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,
    ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”

(D)Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni,
    lọ sí orí òkè gíga.
Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu,
    gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo,
gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù;
    sọ fún àwọn ìlú u Juda,
    “Ọlọ́run rẹ nìyìí!”
10 (E)Wò ó, Olúwa Olódùmarè náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára,
    apá rẹ̀ sì ń jẹ ọba fún un.
Wò ó, èrè rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,
    àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá.
11 Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn:
    Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀.
Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀;
    ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní.

Romu 8:22-25

22 (A)Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá ni ó jùmọ̀ ń kérora tí ó sì ń rọbí pọ̀ títí di ìsinsin yìí. 23 (B)Kì í ṣe àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkára wa pẹ̀lú, a ni àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkára wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìsọdọmọ àní ìdáǹdè ara wa. 24 (C)Nítorí nípa ìrètí ni a fi gbà wá là: ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í ṣe ìrètí nítorí ta ni ń retí ohun tí ó bá rí? 25 Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.