Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.
127 Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà
àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;
bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.
2 Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù
láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;
bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.
3 Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa:
ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.
4 Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe
5 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;
ojú kì yóò tì wọ́n,
ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.
Boasi gbé Rutu ní ìyàwó
4 Nígbà náà ni Boasi gòkè lọ sí ẹnu ibodè ìlú, ó sì jókòó síbẹ̀. Nígbà tí ìbátan tí ó súnmọ́ Elimeleki jùlọ, arákùnrin tí Boasi ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń kọjá, Boasi pè é wí pé, “Máa bọ̀ wá síbí ìwọ ọ̀rẹ́ mi, kí o sì jókòó.” Ó sì lọ jókòó.
2 Boasi sì pe mẹ́wàá nínú àwọn àgbàgbà ìlú, wí pé ki wọn jókòó, wọn sí ṣe bẹ́ẹ̀, 3 ó sì sọ fún ìbátan rẹ̀ náà pé, “Arábìnrin Naomi tí ó dé láti ilẹ̀ Moabu fẹ́ ta ilẹ̀, èyí tí ó ṣe ti arákùnrin Elimeleki wa. 4 Mó sì rò wí pé ó yẹ kí n mú ọ̀rọ̀ náà wá sí etí ìgbọ́ rẹ, wí pé kí o rà á ní iwájú gbogbo àwọn tí ó jókòó sí ibi yìí. Bí ìwọ yóò bá rà á padà rà á. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ní rà á padà, sọ fún mi, kí èmi ó le è mọ̀. Nítorí pé kò sí ẹlòmíràn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á ju ìwọ lọ, èmi sì ni ẹni tí ó tún kàn lẹ́yìn rẹ̀.”
Ọkùnrin náà sì sọ wí pé, “Èmi yóò rà á padà.”
5 Nígbà náà ni Boasi sọ wí pé, “Bí ìwọ bá ti ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Naomi àti lọ́wọ́ Rutu ará Moabu, ìwọ gbọdọ̀ fẹ́ opó ọkùnrin náà, kí orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà má ba à parẹ́ pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ àti kí o le è bímọ ní orúkọ rẹ̀.”
6 Nígbà náà ni ọkùnrin náà dáhùn sí èyí pé, “Nípa ti èyí, èmi kò le è rà á padà, nítorí pé, ọmọ rẹ̀, ọkùnrin yóò wá jẹ́ ajogún àwọn ohun ìní mi pẹ̀lú. Rà á fún ara rẹ, èmi kò le ṣe é.”
7 (A)Ní ayé ìgbàanì, kí a tó le sọ wí pé ohun ìràpadà tàbí pàṣípàrọ̀ ohun ìní fi ìdí múlẹ̀ ní ilẹ̀ Israẹli, ẹnìkan ni láti yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó sì fi fún ẹnìkejì, ó jẹ́ òfin fún ẹni tí ó fẹ́ rà á. Nípa ṣíṣe èyí, àwọn ará Israẹli fihàn wí pé ọ̀rọ̀ náà ti fìdímúlẹ̀.
8 Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin náà sọ fún Boasi wí pé, “Ìwọ rà á fúnrarẹ̀,” ó yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀.
9 Nígbà náà ni Boasi wí fún àwọn àgbàgbà àti àwọn mìíràn tí ó wà ní ibẹ̀ pé, “Gbogbo yín jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní òní wí pé mo ti ra ohun gbogbo tí í ṣe ti Elimeleki àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì: Maloni àti Kilioni lọ́wọ́ Naomi. 10 Ní àfikún, mo ra Rutu ará Moabu opó Maloni padà láti di aya mi. Èyí tí yóò mú kí orúkọ ọkùnrin òkú náà wà pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀, kí ìran rẹ̀ má ba à lè parẹ́ láàrín àwọn ẹbí rẹ̀ àti ìlú rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ní òní.”
6 Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kristi kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run. 7 Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo: ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú. 8 (A)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.
9 (B)Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinsin yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípasẹ̀ rẹ̀. 10 (C)Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀. 11 (D)Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.