Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ti Dafidi.
28 Ìwọ Olúwa,
mo ké pe àpáta mi;
Má ṣe kọ etí dídi sí mi.
Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,
èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.
2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,
bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè
sí ibi mímọ́ rẹ jùlọ.
3 Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,
pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn
ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.
4 San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn
àti fún iṣẹ́ ibi wọn;
gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;
kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.
5 Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
òun ó rún wọn wọlẹ̀
kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.
6 Alábùkún fún ni Olúwa!
Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7 Olúwa ni agbára mi àti asà mi;
nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.
Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀
àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.
8 Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀
òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni ààmì òróró rẹ̀.
9 Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ;
di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.
9 Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa,
àti tí òdodo kò fi tẹ̀ wá lọ́wọ́.
A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ jẹ́ òkùnkùn;
ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji.
10 Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri
tí a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú.
Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni;
láàrín alágbára àwa dàbí òkú.
11 Gbogbo wa là ń ké bí i beari;
àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbà
A ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ́nà
fún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré.
12 Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ,
àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá.
Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa,
àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa,
13 ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí Olúwa,
kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run,
dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀,
pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbèrò síta.
14 Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn,
àti ti òdodo dúró lókèèrè;
òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà,
òdodo kò sì le è wọlé.
15 A kò rí òtítọ́ mọ́,
àti ẹni tí ó bá sá fun ibi tì di ìjẹ.
Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́
pé kò sí ìdájọ́ òdodo.
16 Òun rí i pé kò sí ẹnìkan,
àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́;
nítorí apá òun tìkára rẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀,
àti òdodo òun tìkára rẹ̀ ló gbé e ró.
17 (A)Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàyà rẹ̀,
àti àṣíborí ìgbàlà ní orí rẹ̀;
ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀
ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.
18 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe,
bẹ́ẹ̀ ni yóò san án
ìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀
àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;
òun yóò san án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn.
19 (B)Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,
àti láti ìlà-oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀.
Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omi
èyí tí èémí Olúwa ń tì lọ.
2 Nítorí náà, ẹ fi àrankàn gbogbo sílẹ̀ ni apá kan, àti ẹ̀tàn gbogbo, àti àgàbàgebè, àti ìlara, àti sísọ ọ̀rọ̀ búburú gbogbo. 2 Bí ọmọ ọwọ́ tuntun, kí ẹ máa fẹ́ wàrà ti Ẹ̀mí, èyí tí kò lẹ́tàn, kí ẹ̀yin lè máa tipasẹ̀ rẹ̀ dàgbà sí ìgbàlà, 3 (A)nísinsin yìí tí ẹ̀yin ti tọ́ ọ wò pé rere ni Olúwa.
Àpáta iyè àti ènìyàn tí a yàn
4 (B)Ẹni tí ẹ̀yin ń tọ̀ bọ̀, sí bi òkúta ààyè náà, èyí ti a ti ọwọ́ ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àṣàyàn òkúta iyebíye. 5 Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jesu Kristi. 6 (C)Nítorí nínú Ìwé Mímọ́, ó wí pe:
“Kíyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta igun ilé àṣàyàn,
iyebíye, lélẹ̀ ni Sioni:
ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́
ojú kì yóò tì í.”
7 (D)Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́,
“Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
òun ni ó di pàtàkì igun ilé,”
8 (E)àti pẹ̀lú,
“Òkúta ìdìgbòlù,
àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.”
Nítorí wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.
9 (F)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn olú àlùfáà, Orílẹ̀-èdè mímọ́, Ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọláńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn: 10 (G)Ẹ̀yin tí kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ti di ènìyàn Ọlọ́run, ẹ̀yin tí kò rí àánú gbà rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ ti rí àánú gbà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.