Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ.
34 Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;
ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.
2 Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;
jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.
3 Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;
kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.
4 Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;
Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.
5 Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;
ojú kò sì tì wọ́n.
6 Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀;
ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
7 Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká
ó sì gbà wọ́n.
8 Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;
ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.
19 Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,
ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.
20 Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;
kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.
21 Ibi ni ó mú ikú ìkà wá,
àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.
22 Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà;
kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.
Àdúrà Nehemiah
1 Ọ̀rọ̀ Nehemiah ọmọ Hakaliah:
Ní oṣù Kisleu ní ogún ọdún (ìjọba Ahaswerusi ọba Persia) nígbà tí mo wà ní ààfin Susa, 2 Hanani, ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin mi wá láti Juda pẹ̀lú àwọn ọkùnrin kan, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn nípa àwọn Júù tí ó ṣẹ́kù tí wọn kò kó ní ìgbèkùn, àti nípa Jerusalẹmu.
3 Wọ́n sọ fún mi pé, “Àwọn tí ó kù tí a kó ní ìgbèkùn tí wọ́n sì padà sí agbègbè ìjọba wà nínú wàhálà púpọ̀ àti ẹ̀gàn. Odi Jerusalẹmu ti wó lulẹ̀ a sì ti fi iná sun ẹnu ibodè rẹ̀.”
4 Nígbà tí mo gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo jókòó mo sì sọkún. Mo ṣọ̀fọ̀, mo gbààwẹ̀, mo sì gbàdúrà fún ọjọ́ díẹ̀ níwájú Ọlọ́run ọ̀run. 5 Nígbà náà ni mo wí pé:
“Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, Ọlọ́run tí ó tóbi tí ó sì ní ẹ̀rù, tí ó ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn tí ó fẹ́ ẹ tí wọ́n sì ń pa àṣẹ mọ́. 6 Jẹ́ kí etí rẹ kí ó ṣí sílẹ̀, kí ojú ù rẹ kí ó sì ṣí sílẹ̀ láti gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní iwájú rẹ ní ọ̀sán àti ní òru fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwa ọmọ Israẹli àti tèmi àti ti ilé baba mi, tí a ti ṣẹ̀ sí ọ. 7 Àwa ti ṣe búburú sí ọ. A kò sì pa àṣẹ ìlànà àti òfin tí ìwọ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ mọ́.
8 “Rántí ìlànà tí o fún Mose ìránṣẹ́ rẹ, wí pé, ‘Bí ìwọ bá jẹ́ aláìṣòótọ́, èmi yóò fọ́n yín ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè. 9 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá yípadà sí mi, tí ẹ bá sì pa àṣẹ mi mọ́, nígbà náà bí àwọn ènìyàn yín tí a kó ní ìgbèkùn tilẹ̀ wà ní jìnnà réré ìpẹ̀kun ọ̀run, èmi yóò kó wọn jọ láti ibẹ̀, èmi yóò sì mú wọn wá, sí ibi tí èmi ti yàn bí i ibùgbé fún orúkọ mi.’
10 “Àwọn ni ìránṣẹ́ rẹ àti ènìyàn rẹ àwọn tí ìwọ rà padà pẹ̀lú agbára ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára ńlá rẹ. 11 Olúwa, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sílẹ̀ sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ yìí, àti sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ní inú dídùn láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ. Fún ìránṣẹ́ rẹ ní àṣeyọrí lónìí kí o sì ṣíjú àánú wò ó níwájú Ọkùnrin yìí.”
Nítorí tí mo jẹ́ agbọ́tí ọba nígbà náà.
Jesu fẹ́ràn Melkisedeki
11 (A)Ǹjẹ́ ìbá ṣe pé pípé ń bẹ nípa oyè àlùfáà Lefi, (nítorí pé lábẹ́ rẹ̀ ni àwọn ènìyàn gba òfin), kín ni ó sì tún kù mọ́ tí àlùfáà mìíràn ìbá fi dìde ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Melkisedeki, tí a kò si wí pé ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Aaroni? 12 Nítorí pé bí a ti ń pààrọ̀ iṣẹ́ àlùfáà, a kò sì lè ṣàì máa pààrọ̀ òfin. 13 Nítorí ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, láti inú èyí tí ẹnikẹ́ni kò tì jọ́sìn rí níbi pẹpẹ. 14 Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Juda ni Olúwa wa ti dìde; nípa ẹ̀yà yìí Mose kò sọ ohunkóhun ní ti àwọn àlùfáà. 15 Ó sì tún hàn gbangba ju bẹ́ẹ̀ lọ bí ó ti jẹ pé àlùfáà mìíràn dìde ní àpẹẹrẹ ti Melkisedeki. 16 Èyí tí a fi jẹ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin nípa ti ara, bí kò ṣe nípa agbára ti ìyè àìlópin. 17 Nítorí a jẹ́rìí pé:
“Ìwọ ni àlùfáà títí láé
ní ipasẹ̀ ti Melkisedeki.”
18 Nítorí a mú òfin ìṣáájú kúrò nítorí àìlera àti àìlérè rẹ̀. 19 (Nítorí òfin kò mú ohunkóhun pé), a sì mú ìrètí tí ó dára jù wá nípa èyí tí àwa ń súnmọ́ Ọlọ́run.
20 Níwọ́n bí ó sì ti ṣe pé kì í ṣe ní àìbúra ni. Nítorí àwọn àlùfáà tẹ́lẹ̀ jẹ oyè láìsí ìbúra, 21 ṣùgbọ́n ti òun jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nígbà tí Ọlọ́run wí fún un pé,
“Olúwa búra,
kí yóò sì yí padà:
‘Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé ni ipasẹ̀ ti Mekisédékì.’ ”
22 Níwọ́n bẹ́ẹ̀ ni Jesu ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.