Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 75

Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin.

75 A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,
    a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí;
    àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.

Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;
    Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.
Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,
    Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.
Èmí wí fún àwọn agbéraga pé
    Ẹ má ṣe gbéraga mọ́;
àti sí ènìyàn búburú;
    Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.
Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;
    ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”

Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá
    tàbí ní ìwọ̀-oòrùn,
    bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́;
    Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.
Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,
    ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú,
ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde,
    àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.

Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé;
    Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.
10 Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,
    Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.

Jobu 41:1-11

Ọlọ́run ń tẹ̀síwájú láti pe Jobu níjà

41 “Ǹjẹ́ ìwọ le è fi ìwọ̀ fa Lefitani jáde?
    Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?
Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní í mú,
    tàbí fi ìwọ̀ ẹ̀gún gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́?
Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀
    rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́?
Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí?
    Ìwọ ó ha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí?
Ìwọ ha lè ba sáré bí ẹni pé ẹyẹ ni,
    tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀?
Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà á bí?
    Wọn ó ha pín láàrín àwọn oníṣòwò?
Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin gun awọ rẹ̀,
    tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ìpẹja.
Fi ọwọ́ rẹ lé e lára,
    ìwọ ó rántí ìjà náà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
Kíyèsi, ìgbìyànjú láti mú un ní asán;
    ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì?
10 Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè;
    Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi.
11 Ta ni ó kọ́kọ́ ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san án fún un?
    Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.

Heberu 6:13-20

Ìdánilójú ìlérí Ọlọ́run

13 (A)Nítorí nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Abrahamu, bí kò ti rí ẹni tí ó pọ̀jù òun láti fi búra, ó fi ara rẹ̀ búra, wí pé, 14 “Nítòótọ́ ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i.” 15 Bẹ́ẹ̀ náà sì ni, lẹ́yìn ìgbà tí Abrahamu fi sùúrù dúró, ó ri ìlérí náà gbà.

16 Nítorí ènìyàn a máa fi ẹni tí ó pọ̀jù wọ́n lọ búra: ìbúra náà a sì fi òpin sí gbogbo ìjiyàn wọn fún ìfẹ̀sẹ̀ múlẹ̀ ọ̀rọ̀. 17 Nínú èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí ń fẹ́ gidigidi láti fi àìlèyípadà ète rẹ̀ hàn fún àwọn ajogún ìlérí náà, ó fi ìbúra sáàrín wọn. 18 Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú ṣinṣin: 19 (B)Èyí tí àwa níbi ìdákọ̀ró ọkàn fún ọkàn wa, ìrètí tí ó dájú tí ó sì dúró ṣinṣin, tí ó sì wọ inú ilé lọ lẹ́yìn aṣọ ìkélé; 20 (C)níbi tí Jesu, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ alábojútó àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.