Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 104:1-9

104 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ;
    ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.

Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ;
    ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní
Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ.
    Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ
    ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
(A)Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
    Ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.

O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;
    tí a kò le è mì láéláé.
Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ;
    àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.
Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ,
    nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ;
Wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè,
    wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀,
    sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.
Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀;
    láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.

Saamu 104:24

24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!
    Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:
    ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.

Saamu 104:35

35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé
    kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.

Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Yin Olúwa.

Jobu 39

Agbára Ọlọ́run

39 “Ìwọ mọ àkókò ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ?
    Ìwọ sì lè kíyèsi ìgbà tí abo àgbọ̀nrín ń bímọ?
Ìwọ lè ka iye òṣùpá tí wọn ń pé,
    ìwọ sì mọ àkókò ìgbà tí wọn ń bímọ,
Wọ́n tẹ ara wọn ba, wọ́n bímọ,
    wọ́n sì mú ìkáàánú wọn jáde.
Àwọn ọmọ wọn rí dáradára, wọ́n dàgbà nínú ọ̀dàn;
    wọ́n jáde lọ, wọn kò sì tún padà wá sọ́dọ̀ wọn.

“Ta ni ó jọ̀wọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ oko lọ́wọ́?
    Tàbí ta ní ó tú ìdè kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó,
Èyí tí mo fi aginjù ṣe ilé fún,
    àti ilẹ̀ iyọ̀ ní ibùgbé rẹ̀.
Ó rẹ́rìn-ín sí ariwo ìlú,
    bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbọ́ igbe darandaran.
Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjẹ oko rẹ̀,
    Òun a sì máa wá ewé tútù gbogbo rí.

“Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí?
    Tàbí ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru?
10 Ìwọ le fi Òkun tata de àgbáǹréré nínú aporo?
    Tàbí ó jẹ́ máa fa ìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn?
11 Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀lé e nítorí agbára rẹ̀ pọ̀?
    Ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́?
12 Ìwọ le gbẹ́kẹ̀lé pé, yóò mú èso oko rẹ̀ wá sílé,
    àti pé yóò sì kó ọ jọ sínú àká rẹ?

13 “Ìwọ ni yóò ha fi ìyẹ́ dáradára fún ọ̀kín bí,
    tàbí ìyẹ́ àti ìhùhù bo ògòǹgò?
14 Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀,
    a sì mú wọn gbóná nínú ekuru;
15 Tí ó sì gbàgbé pé, ẹsẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́,
    tàbí pé ẹranko igbó lè tẹ̀ wọ́n fọ́.
16 Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bí ẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀;
    asán ni iṣẹ́ rẹ̀ láìní ìbẹ̀rù;
17 Nítorí pé Ọlọ́run kò fún un ní ọgbọ́n,
    bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un.
18 Nígbà tí ó gbé ara sókè,
    ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin.

19 “Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí,
    tàbí ṣé ìwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ?
20 Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà?
    Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá.
21 Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú Àfonífojì, ó sì yọ̀ nínú agbára rẹ̀;
    ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun.
22 Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kò sì fò ó;
    bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà.
23 Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹ́kẹ́pẹ́kẹ́,
    àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.
24 Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbé ilé mi,
    bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbà á gbọ́ pé, ìró ìpè ni.
25 Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà!
    Ó sì gbóhùn ogun lókèèrè réré,
    igbe àwọn balógun àti ìhó ayọ̀ ogun wọn.

26 “Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fò sókè,
    tí ó sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúúsù?
27 Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè,
    kí ó sì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga?
28 Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta,
    lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè.
29 Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ kiri,
    ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré.
30 Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú a máa mu ẹ̀jẹ̀,
    níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ ni òun wà pẹ̀lú.”

Luku 22:24-30

24 (A)Ìjà kan sì ń bẹ láàrín wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí nínú wọn. 25 (B)Ó sì wí fún wọn pé, “Àwọn ọba aláìkọlà a máa fẹlá lórí wọn: a sì máa pe àwọn aláṣẹ wọn ní olóore. 26 (C)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí ẹni tí o kéré ju àbúrò; ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. 27 Nítorí ta ni ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí oúnjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí? Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrín yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. 28 (D)(E)Ẹ̀yin ni àwọn tí ó ti dúró tì mí nínú ìdánwò mi. 29 (F)Mo sì yan ìjọba fún yín, gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti yàn fún mi: 30 (G)Kí ẹ̀yin lè máa jẹ, kí ẹ̀yin sì lè máa mu lórí tábìlì mi ní ìjọba mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.