Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
104 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ;
ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.
2 Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ;
ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní
3 Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ.
Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ
ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
4 (A)Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
Ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.
5 O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;
tí a kò le è mì láéláé.
6 Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ;
àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.
7 Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ,
nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ;
8 Wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè,
wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀,
sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.
9 Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀;
láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.
24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!
Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:
ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.
35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé
kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
Yin Olúwa.
Ọlọ́run kì í pọ́n ni lójú láìnídìí
37 “Àyà sì fò mi sí èyí pẹ̀lú,
ó sì kúrò ní ipò rẹ̀.
2 Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀,
àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.
3 Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo,
Mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.
4 Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù;
ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá.
Òhun kì yóò sì dá àrá dúró,
nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.
5 Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu;
ohùn ńláńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.
6 Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’
àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’
7 Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀,
ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.
8 Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ,
wọn a sì wà ni ipò wọn.
9 Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá,
àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.
10 Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni,
ibú omi á sì súnkì.
11 Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo,
a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.
12 Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀,
kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun
tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.
13 Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀,
tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
14 “Jobu, dẹtí sílẹ̀ sí èyí;
dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.
15 Ṣe ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run ṣe wọ́n lọ́jọ̀,
tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọsánmọ̀ rẹ̀ dán?
16 Ṣé ìwọ mọ ìgbà tí àwọsánmọ̀ í fò lọ,
iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?
17 Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná,
nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́.
18 Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin,
tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà?
19 “Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un;
nítorí pé àwa kò le wádìí ọ̀rọ̀ náà nítorí òkùnkùn wa.
20 A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀?
Tàbí ẹnìkan lè wí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbé mi mì?
21 Síbẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò rí
oòrùn tí ń dán nínú àwọsánmọ̀,
ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì gbá wọn mọ́.
22 Wúrà dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá;
lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rù ńlá wa.
23 Nípa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀, ó rékọjá ní ipá;
nínú ìdájọ́ àti títí bi òun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́.
24 Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀,
òun kì í ṣe ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé?”
Obìnrin àti ẹranko
17 (A)Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje náà tí ó ní ìgò méje wọ̀n-ọn-nì sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín; èmi ó sì fi ìdájọ́ àgbèrè ńlá ní tí ó jókòó lórí omi púpọ̀ han ọ: 2 (B)Ẹni tí àwọn ọba ayé bá ṣe àgbèrè, tí a sì fi ọtí wáìnì àgbèrè rẹ̀ pa àwọn tí ń gbé inú ayé.”
3 Ó sì gbé mi nínú ẹ̀mí lọ sí aginjù: mo sì rí obìnrin kan ó jókòó lórí ẹranko aláwọ̀ òdòdó kan tí ó kún fún orúkọ ọ̀rọ̀-òdì, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. 4 (C)A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ òdòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti perli ṣe é ní ọ̀ṣọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbèrè rẹ̀; 5 àti níwájú rẹ̀ ni orúkọ kan tí a kọ:
ohun ìjìnlẹ̀ babeli ńlá
ìyá àwọn panṣágà
àti àwọn ohun ìríra ayé.
6 Mo sì rí obìnrin náà mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ajẹ́rìí ikú Jesu ní àmuyó.
Nígbà tí mo sì rí i, ẹnu yà mi gidigidi. 7 Angẹli sì wí fún mi pé, “Nítorí kí ni ẹnu ṣe yà ọ́? Èmi ó sọ ti ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ, àti ti ẹranko tí ó gùn, ti ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. 8 (D)Ẹranko tí ìwọ ri nì, o ti wà, kò sì ṣí mọ́: Yóò sì ti inú ọ̀gbun gòkè wá, yóò sì lọ sínú ìparun rẹ. Àwọn olùgbé ayé ti a kọ orúkọ wọn sínú ìwé iye láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, nígbà tí wọn ń wò ẹranko tí o ti wà, tí kò sì ṣí mọ́, tí ó sì ń bọ̀ wá, ẹnu si ya wọn.
9 “Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà. Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó. 10 Ọba méje sì ní wọn: àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé; nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú. 11 Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì ṣí, òun náà sì ni ẹ̀kẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun.
12 (E)“Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí ni ọba mẹ́wàá ni wọn, tí wọn kò ì ti gba ìjọba; ṣùgbọ́n wọn gba àṣẹ bí ọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan. 13 Àwọn wọ̀nyí ní inú kan, wọ́n yóò sì fi agbára àti ọlá wọn fún ẹranko náà. 14 (F)Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́-Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn: nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti ọba àwọn ọba: Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtítọ́ yóò sì ṣẹ́gun pẹ̀lú.”
15 Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn omi tí ìwọ ti rí ni, níbi tí àgbèrè náà jókòó, àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti orílẹ̀ àti onírúurú èdè ni wọ́n. 16 Àti ìwo mẹ́wàá tí ìwọ rí, àti ẹranko náà, àwọn wọ̀nyí ni yóò kórìíra àgbèrè náà, wọn ó sì sọ ọ́ di ahoro àti ẹni ìhòhò, wọn ó sì jẹ ẹran-ara rẹ̀, wọn ó sì fi iná sun ún pátápátá. 17 Nítorí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn wọn láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, láti ní inú kan, àti láti fi ìjọba wọn fún ẹranko náà, títí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi ṣẹ 18 Obìnrin tí ìwọ rí ní ìlú ńlá ni, tí ń jẹ ọba lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.