Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
104 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ;
ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.
2 Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ;
ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní
3 Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ.
Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ
ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
4 (A)Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
Ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.
5 O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;
tí a kò le è mì láéláé.
6 Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ;
àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.
7 Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ,
nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ;
8 Wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè,
wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀,
sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.
9 Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀;
láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.
24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!
Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:
ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.
35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé
kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
Yin Olúwa.
36 Elihu sì tún sọ̀rọ̀ wí pé:
2 “Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fihàn ọ́,
nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.
3 Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jíjìn wá,
èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.
4 Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké
nítòótọ́; ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.
5 “Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì
gàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye.
6 Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí,
ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.
7 Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo,
ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́;
àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.
8 Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí a
sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,
9 Nígbà náà ni ó ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn,
wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga wọn.
10 Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́,
ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedédé.
11 Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín,
wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀rùn,
àti ọdún wọn nínú afẹ́.
12 Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́,
wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé,
wọ́n á sì kú láìní òye.
13 “Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ;
wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí.
14 Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe,
ní àárín àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà.
15 Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn,
a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn.
16 “Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó fa wọn yọ láti inú ìhágágá sí ibi gbòòrò,
sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀,
ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.
7 Nítorí náà ẹ gba ara yín mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti gbà wá mọ́ra fún ògo Ọlọ́run. 8 Mo sì wí pé, a rán Kristi láti ṣe ìránṣẹ́ ìkọlà àwọn tí ṣe Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀, 9 (A)kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrín àwọn Kèfèrí,
Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.”
10 (B)Ó sì tún wí pé,
“Ẹ̀yin Kèfèrí, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.”
11 (C)Àti pẹ̀lú,
“Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Kèfèrí;
ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.”
12 (D)Isaiah sì tún wí pé,
“Gbòǹgbò Jese kan ń bọ̀ wá,
òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn Kèfèrí;
Àwọn Kèfèrí yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.”
13 Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.