Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 39

Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi.

39 Mo wí pé, “èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi
    kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀;
èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu
    níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”
Mo fi ìdákẹ́ ya odi;
    mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;
ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.
    Àyà mi gbóná ní inú mi.
Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn;
    nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:

Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,
    àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí
    kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.
Ìwọ ti ṣe ayé mi
    bí ìbú àtẹ́lẹwọ́,
ọjọ́ orí mi sì dàbí asán
    ní iwájú rẹ:
Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú
    ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.

“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.
    Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;
wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,
    wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.

“Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,
    Olúwa,
kín ni mo ń dúró dè?
    Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.
Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.
    Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn
àwọn ènìyàn búburú.
Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;
    èmi kò sì ya ẹnu mi,
nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.
10 Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi;
    èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.
11 Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀
    fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,
ìwọ a mú ẹwà rẹ parun
    bí kòkòrò aṣọ;
nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.

12 “Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,
    kí o sì fetí sí igbe mi;
kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi
    nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ
àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.
13 Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,
    kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí,
    àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”

Jobu 26

Ìdáhùn Jobu

26 Ṣùgbọ́n Jobu sì dáhùn wí pé:

Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tí kò ní ipá,
    báwo ní ìwọ ń ṣe gbe apá ẹni tí kò ní agbára?
Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ fun ẹni tí kò ní ọgbọ́n,
    tàbí báwo òye rẹ to pọ to bẹ́ẹ̀?
Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,
    àti ẹ̀mí ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀?

“Àwọn aláìlágbára ti isà òkú wárìrì,
    lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Ìhòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run,
    ibi ìparun kò sí ní ibojì.
Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú,
    ó sì so ayé rọ̀ ní ojú asán.
Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn;
    àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.
Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn,
    ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí.
10 Ó fi ìdè yí omi Òkun ká,
    títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.
11 Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì,
    ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀.
12 Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi Òkun;
    nípa òye rẹ̀, ó gé agbéraga sí wẹ́wẹ́.
13 Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́;
    ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì.
14 Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀;
    ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó!
    Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”

Ìfihàn 7:9-17

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn nínú ẹ̀wù funfun

Lẹ́yìn náà, mo ri, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò lè kà, láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti láti inú èdè gbogbo wá, wọn dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, a wọ̀ wọ́n ni aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ si ń bẹ ni ọwọ́ wọn. 10 Wọ́n sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:

“Ìgbàlà ni ti Ọlọ́run wá
tí o jókòó lórí ìtẹ́,
àti ti Ọ̀dọ́-àgùntàn!”

11 Gbogbo àwọn angẹli sì dúró yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn àgbà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ká, wọn wólẹ̀ wọn si dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà wọ́n sì sin Ọlọ́run. 12 Wí pe:

“Àmín!
Ìbùkún, àti ògo,
àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá,
àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé!
Àmín!”

13 Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà si dáhùn, ó bi mí pé, “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí a wọ ni aṣọ funfun? Níbo ni wọn sì ti wá?”

14 (A)Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.”

Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà. 15 Nítorí náà ni,

“wọn ṣe ń bẹ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run,
    tí wọn sì ń sìn ín, lọ́sàn àti lóru nínú tẹmpili rẹ̀;
ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́ náà yóò si ṣíji bò wọn.
16 (B)Ebi kì yóò pa wọn mọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ́ wọ́n mọ́;
bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọn
    tàbí oorukóoru kan.
17 (C)Nítorí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń bẹ ni àárín ìtẹ́ náà ni yóò máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn wọn,
    ‘tí yóò sì máa ṣe amọ̀nà wọn sí ibi orísun omi ìyè:’
‘Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.