Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 22:1-15

Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi.

22 (A)Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?
    Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là,
    àní sí igbe ìkérora mi?
Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:
    àti ní òru èmi kò dákẹ́.

Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni ìwọ;
    ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó;
Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ;
    wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.
Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà;
    ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.

Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn;
    mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn
Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà;
    wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.
“Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa;
    jẹ́ kí Olúwa gbà á là.
Jẹ́ kí ó gbà á là,
    nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”

Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;
    ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu, nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.
10 Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá,
    nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi.

11 Má ṣe jìnnà sí mi,
    nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí
    kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.

12 Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;
    àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká.
13 Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri,
    tí ń ké ramúramù.
14 A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,
    gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀.
Ọkàn mi sì dàbí i ìda;
    tí ó yọ́ láàrín inú mi.
15 Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,
    ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;
    ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.

Jobu 20

Ìdáhùn Sofari

20 Ìgbà náà ní Sofari, ará Naama dáhùn, ó sì wí pé:

“Nítorí náà ní ìrò inú mi dá mi lóhùn,
    àti nítorí èyí náà ní mo sì yára si gidigidi.
Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi, ẹ̀mí òye
    mi sì dá mi lóhùn.

“Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́,
    láti ìgbà tí a sọ ènìyàn lọ́jọ̀ sílé ayé,
pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbà kúkúrú ni,
    àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè?
Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run,
    ti orí rẹ̀ sì kan àwọsánmọ̀;
Ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀;
    àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’
Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i,
    àní a ó lé e lọ bi ìran òru.
Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́.
10 Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojúrere lọ́dọ̀ tálákà,
    ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà.
11 Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀,
    tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀.

12 “Bí ìwà búburú tilẹ̀ dún ní ẹnu rẹ̀,
    bí ó tilẹ̀ pa á mọ́ nísàlẹ̀ ahọ́n rẹ̀,
13 bí ó tilẹ̀ dá a sì, tí kò si kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
    tí ó pa á mọ́ síbẹ̀ ní ẹnu rẹ̀,
14 Ṣùgbọ́n oúnjẹ rẹ̀ nínú ikùn rẹ̀ ti yípadà,
    ó jásí òróró paramọ́lẹ̀ nínú rẹ̀;
15 Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde;
    Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá.
16 Ó ti fà oró paramọ́lẹ̀ mú;
    ahọ́n ejò olóró ní yóò pa á.
17 Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì,
    ìṣàn omi, odò tí ń ṣàn fún oyin àti ti òrí-àmọ́.
18 Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì;
    gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì ìgbádùn nínú rẹ̀.
19 Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni tálákà lára, ó sì ti kẹ́hìndà wọ́n;
    Nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́.

20 “Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀,
    kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀.
21 Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀;
    Nítorí náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì yóò dúró pẹ́.
22 Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a;
    àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́jọ lé e lórí.
23 Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun,
    Ọlọ́run yóò fà ríru ìbínú rẹ̀ sí í lórí, nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́,
    yóò sì rọ òjò ìbínú rẹ̀ lé e lórí.
24 Bi o tilẹ̀ sá kúrò lọ́wọ́ ohun ìjà ìrìn;
    ọrun akọ irin ní yóò ta a po yọ.
25 O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára;
    idà dídán ní ń jáde láti inú òróòro wá.
Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀;
26     òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀.
Iná ti a kò fẹ́ ní yóò jó o run
    yóò sì jẹ èyí tí ó kù nínú àgọ́ rẹ̀ run.
27 Ọ̀run yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn,
    ayé yóò sì dìde dúró sí i.
28 Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ, àti ohun
    ìní rẹ̀ yóò sàn dànù lọ ni ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.
29 Èyí ni ìpín ènìyàn búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá,
    àti ogún tí a yàn sílẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”

Matiu 15:1-9

Ohun mímọ́ àti ohun àìmọ́

15 (A)Nígbà náà ní àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin tọ Jesu wá láti Jerusalẹmu, wọn béèrè pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ fi ń rú òfin àtayébáyé àwọn alàgbà? Nítorí tí wọn kò wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun!”

Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Èéha ṣe tí ẹ̀yin fi rú òfin Ọlọ́run, nítorí àṣà yín? Nítorí Ọlọ́run wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún Baba òun ìyá rẹ,’ àti pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí baba tàbí ìyá rẹ̀, ní láti kú.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún baba tàbí ìyá rẹ̀ pé, ‘Ẹ̀bùn fún Ọlọ́run ni ohunkóhun tí ìwọ ìbá fi jèrè lára mi;’ Tí Òun kò sì bọ̀wọ̀ fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ó bọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin sọ òfin Ọlọ́run di asán nípa àṣà yín. Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Isaiah sọtẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:

(B)“ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi,
    ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi.
Lásán ni ìsìn wọn;
    nítorí pé wọ́n ń fi òfin ènìyàn kọ́ ni ní ẹ̀kọ́.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.