Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi.
55 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,
Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:
2 Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.
Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.
3 Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni,
nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;
nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi,
wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.
4 Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú;
ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.
5 Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi;
ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.
6 Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!
Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.
7 Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré,
kí ń sì dúró sí aginjù;
8 Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,
jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”
9 Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú,
nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.
10 Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri;
ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.
11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀;
ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.
12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,
èmi yóò fi ara mọ́ ọn;
tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi,
èmi ìbá sápamọ́ fún un.
13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,
ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,
14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,
bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.
15 Kí ikú kí ó dé bá wọn,
Kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú,
Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,
nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.
Elifasi tako ọrọ̀ Jobu
15 Ìgbà náà ní Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé:
2 “Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asán, kí
ó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn kún ara rẹ̀ nínú?
3 Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò ní
èrè, tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere?
4 Ṣùgbọ́n ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì,
ìwọ sì dí iṣẹ́ ìsìn lọ́nà níwájú Ọlọ́run.
5 Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀
rẹ̀, ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò.
6 Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi;
àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí gbè ọ́.
7 “Ìwọ ha í ṣe ọkùnrin tí a kọ́ bí?
Tàbí a ha dá ọ ṣáájú àwọn òkè?
8 Ìwọ gbúròó àṣírí Ọlọ́run rí, tàbí
ìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ?
9 Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀?
Òye kí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa?
10 Àwọn arúgbó àti ògbólógbòó ènìyàn wà pẹ̀lú wa,
tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ.
11 Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ?
Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ?
12 Èéṣe ti ọkàn rẹ fi ń ti ọ kiri,
kí ni ìwọ tẹjúmọ́ tóbẹ́ẹ̀.
13 Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì sí Ọlọ́run,
tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀?
14 “Kí ni ènìyàn tí ó fi jẹ mímọ́,
àti ẹni tí a tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo?
15 Kíyèsi i, bi Ọlọ́run ko ba gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,
àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ojú rẹ̀,
16 mélòó mélòó ni ènìyàn, ẹni ìríra àti eléèérí,
tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mu omi.
17 “Èmi ó fihàn ọ́, gbọ́ ti èmi;
Èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,
18 ohun tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn láti
ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́,
19 Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan,
ti àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.
20 Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá,
pẹ̀lú ìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo,
àti iye ọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára.
21 Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀;
nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i.
22 Kò gbàgbọ́ pé òun ó jáde kúrò nínú òkùnkùn;
a sì ṣà á sápá kan fún idà.
23 Ó ń wò káàkiri fún oúnjẹ wí pé, níbo ní ó wà?
Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn súnmọ́ tòsí.
24 Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú un
bẹ̀rù, wọ́n ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ìmúra ogun.
25 Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdì
sí Ọlọ́run, ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmarè,
26 Ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn gíga,
àní fi ike-kókó àpáta rẹ̀ tí ó nípọn kọlù ú.
27 “Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀
lójú, o sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
28 Òun sì gbé inú ahoro ìlú,
àti nínú ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé
mọ́, tí ó múra tán láti di àlàpà.
29 Òun kò lé di ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kò
lè dúró pẹ́; Bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.
30 Òun kì yóò jáde kúrò nínú òkùnkùn;
ọ̀wọ́-iná ni yóò jó ẹ̀ka rẹ̀,
àti nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu Ọlọ́run ní a ó gba kúrò.
31 Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀lé asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ.
Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.
32 A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípé ọjọ́ rẹ̀,
ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù.
33 Yóò dàbí àjàrà tí a gbọn èso àìpọ́n rẹ̀ dànù,
yóò sì rẹ̀ ìtànná rẹ̀ dànù bí i ti igi Olifi.
34 Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebè
yóò túká, iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
35 Wọ́n lóyún ìwà ìkà, wọ́n sì bí ẹ̀ṣẹ̀,
ikùn wọn sì pèsè ẹ̀tàn.”
Panṣágà
27 (A)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.’ 28 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀. 29 Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè fún ọ kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì. 30 Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì.
Ìkọ̀sílẹ̀
31 (B)“A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, jẹ́ kí ó fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lé e lọ́wọ́.’ 32 Ṣùgbọ́n èmi sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, ó mú un ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ẹni tí a kọ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà.
Ìbúra
33 (C)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ búra èké bí kò ṣe pé kí ìwọ kí ó mú ìbúra rẹ̀ fún Olúwa ṣẹ.’ 34 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, ẹ má ṣe búra rárá: ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni. 35 Tàbí fi ayé búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerusalẹmu, nítorí olórí ìlú ọba Ńlá ni. 36 Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.