Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 55:1-15

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi.

55 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,
    Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:
    Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.
Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.
    Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni,
    nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;
nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi,
    wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.

Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú;
    ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.
Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi;
    ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.
Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!
    Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.
Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré,
    kí ń sì dúró sí aginjù;
Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,
    jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”

Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú,
    nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.
10 Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri;
    ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.
11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀;
    ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.

12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,
    èmi yóò fi ara mọ́ ọn;
tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi,
    èmi ìbá sápamọ́ fún un.
13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,
    ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,
14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,
    bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.

15 Kí ikú kí ó dé bá wọn,
    Kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú,
Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,
    nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.

Jobu 11

Sofari fi ẹ̀sùn irọ́ pípa àti àìṣòótọ́ kan Jobu

11 Ìgbà náà ni Sofari, ará Naama, dáhùn, ó sì wí pé:

“A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀?
    A ha lè fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí da ènìyàn láre?
Ṣé àmọ̀tán rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí?
    Ṣé ẹnikẹ́ni kò ní bá ọ wí bí ìwọ bá yọ ṣùtì sí ni?
Ìwọ sá à ti wí fún Ọlọ́run pé,
    ‘ìṣe mi jẹ́ aláìléérí, èmi sì mọ́ ní ojú rẹ.’
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀,
    kí ó sì ya ẹnu rẹ̀ sí ọ;
Kí ó sì fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ;
    Nítorí náà, mọ̀ pé Ọlọ́run ti
    gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kan.

“Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí?
    Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olódùmarè dé bi?
Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ; kí ni ìwọ le è ṣe?
    Ó jì ju jíjìn isà òkú lọ; kí ni ìwọ le mọ̀?
Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ,
    ó sì ní ibú ju Òkun lọ.

10 “Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sé ọnà,
    tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdájọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́?
11 Òun sá à mọ ẹlẹ́tàn ènìyàn;
    àti pé ṣé bí òun bá rí ohun búburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i?
12 Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn ki yóò di ọlọ́gbọ́n,
    bi ko ti rọrùn fún ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó láti bí ènìyàn.

13 “Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un,
    tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,
14 Bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù,
    tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ.
15 Nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láìní àbàwọ́n,
    àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù,
16 Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ,
    ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ.
17 Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ,
    bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísinsin yìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀.
18 Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà;
    àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.
19 Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́,
    àní ènìyàn yóò máa wá ojúrere rẹ.
20 Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo;
    gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n,
    ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”

1 Kọrinti 7:10-16

10 Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Obìnrin kò gbọdọ̀ kọ́ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.” 11 Ṣùgbọ́n tí ó bá fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀; jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ làjà, kí ọkọ kí ó má ṣe aya rẹ̀ sílẹ̀.

12 (A)Mo fẹ́ fi àwọn ìmọ̀ràn kan kún ún fún un yín, kì í ṣe àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Bí arákùnrin bá fẹ́ aya tí kò gbàgbọ́, tí aya náà sá á fẹ́ dúró tí ọkọ náà, ọkọ náà tí í ṣe onígbàgbọ́ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 13 Tí ó bá sì jẹ́ obìnrin ló fẹ́ ọkọ tí kò gbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí ọkọ náà ń fẹ́ kí obìnrin yìí dúró tí òun, aya náà kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 14 Nítorí pé ó ṣe é ṣe kí a lè mú ọkọ tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa aya tí í ṣe onígbàgbọ́, a sì le mú ìyàwó tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ aláìmọ́. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó ṣe é ṣe kí àwọn ọmọ wọn di mímọ́.

15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin tí i ṣe aláìgbàgbọ́ náà bá fẹ́ láti lọ, jẹ́ kí ó máa lọ. Arákùnrin tàbí arábìnrin náà kò sí lábẹ́ ìdè mọ́; Ọlọ́run ti pè wá láti gbé ní àlàáfíà. 16 (B)Báwo ni ẹ̀yin aya ṣe le mọ̀ pé bóyá ẹ̀yin ni yóò gba ọkọ yín là? Bákan náà ni a lè wí nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́ pé, kò sí ìdánilójú pé aya aláìgbàgbọ́ le yípadà láti di onígbàgbọ́ nípa dídúró ti ọkọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.