Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ti Dafidi.
26 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,
nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,
mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa
Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
2 Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,
dán àyà àti ọkàn mi wò;
3 Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,
èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.
4 Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;
5 Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú
èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
6 Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.
7 Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,
èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
8 Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé,
àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.
9 Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,
10 Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;
rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.
12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;
nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.
Ọ̀rọ̀ Elifasi: Ọlọ́run kì í fi ìyà jẹ olódodo
4 Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani dáhùn wí pé:
2 “Bí àwa bá fi ẹnu lé e, láti bá ọ sọ̀rọ̀, ìwọ o ha banújẹ́?
Ṣùgbọ́n ta ni ó lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹnu láìsọ?
3 Kíyèsi i, ìwọ sá ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn,
ìwọ ṣá ti mú ọwọ́ aláìlera le.
4 Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró,
ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera.
5 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọlù ọ́;
ara rẹ kò lélẹ̀.
6 Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ
àti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ?
7 “Èmi bẹ̀ ọ́ rántí: Ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀?
Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí?
8 Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń ṣe ìtulẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀,
tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà.
9 Nípa ìfẹ́ sí Ọlọ́run wọn a ṣègbé,
nípa èémí ìbínú rẹ̀ wọn a parun.
10 Bíbú ramúramù kìnnìún àti ohùn òǹrorò kìnnìún
àti eyín àwọn ẹgbọrọ kìnnìún ní a ká.
11 Kìnnìún kígbe, nítorí àìrí ohun ọdẹ,
àwọn ẹgbọrọ kìnnìún sísanra ni a túká kiri.
12 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí a fi ohun àṣírí kan hàn fún mi,
etí mi sì gbà díẹ̀ nínú rẹ̀.
13 Ní ìrò inú lójú ìran òru,
nígbà tí oorun èjìká kùn ènìyàn.
14 Ẹ̀rù bà mí àti ìwárìrì
tí ó mú gbogbo egungun mi jí pépé.
15 Nígbà náà ni ẹ̀mí kan kọjá lọ ní iwájú mi,
irun ara mi dìde dúró ṣánṣán.
16 Ó dúró jẹ́ẹ́,
ṣùgbọ́n èmi kò le wo àpẹẹrẹ ìrí rẹ̀,
àwòrán kan hàn níwájú mi,
ìdákẹ́rọ́rọ́ wà, mo sì gbóhùn kan wí pé:
17 ‘Ẹni kíkú le jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run,
ènìyàn ha le mọ́ ju Ẹlẹ́dàá rẹ̀ bí?
18 Kíyèsi i, òun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,
nínú àwọn angẹli rẹ̀ ní ó sì rí ẹ̀ṣẹ̀.
19 Mélòó mélòó àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀,
ẹni tí ìpìlẹ̀ wọ́n jásí erùpẹ̀
tí yóò di rírun kòkòrò.
20 A pa wọ́n run láàrín òwúrọ̀ àti àṣálẹ́
wọ́n sì parun títí láé, láìrí ẹni kà á sí.
21 A kò ha ké okùn iye wọ́n kúrò bí?
Wọ́n kú, àní láìlọ́gbọ́n?’
Ìyè nípasẹ̀ ẹ̀mí
8 (A)Nítorí náà, kò sí ìdálẹ́bi nísinsin yìí fún àwọn tí ó wà nínú Kristi Jesu, àwọn tí kò rìn nípa ti ara, bí kò ṣe nípa ti Ẹ̀mí. 2 (B)Nítorí nípasẹ̀ òfin ti ẹ̀mí ìyè nínú Kristi Jesu ti sọ mí di òmìnira kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. 3 (C)Nítorí ohun tí òfin kò lè ṣe, bí ó ti jẹ aláìlera nítorí ara, Ọlọ́run rán ọmọ òun tìkára rẹ̀ ní àwòrán ara ẹ̀ṣẹ̀, ó sì di ẹ̀ṣẹ̀; àti bi ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nínú ara, 4 (D)kí a lè mú òdodo òfin ṣẹ, nínú wa, nítorí tí àwa yé gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí.
5 (E)Àwọn tí ń gbe nípa ti ara, wọn a máa ronú ohun ti ara; ṣùgbọ́n àwọn ti ń gbe nípa ti Ẹ̀mí, wọn a máa ronú ohun ti Ẹ̀mí. 6 (F)Nítorí èrò ti ara ikú ni; ṣùgbọ́n èrò ti ẹ̀mí ni ìyè àti àlàáfíà. 7 Nítorí èrò ti ara ọ̀tá ni sí Ọlọ́run, nítorí kì í tẹríba fún òfin Ọlọ́run, òun kò tilẹ̀ le ṣe e. 8 (G)Ìdí nìyìí tí àwọn tí ó wà lábẹ́ àkóso ara ẹ̀ṣẹ̀, kò le è tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn.
9 (H)Ṣùgbọ́n ẹyin kò sí nínú ti ara, bí kò ṣe nínú ti Ẹ̀mí, bí ó bá ṣe pé Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín, Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá ní Ẹ̀mí Kristi, òun kò sí nínú ẹni tirẹ̀. 10 (I)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristi ń gbé inú yín síbẹ̀síbẹ̀, ara yín jẹ́ òkú nítorí ẹ̀ṣẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú yín yóò fún yín ní ìyè, nítorí ó ti fún un yín ní òdodo. 11 (J)Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jesu kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, ẹni tí ó jí Kristi Jesu dìde kúrò nínú òkú, yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ tí ń gbé inú yín sọ ara kíkú yín di ààyè pẹ̀lú.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.