Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 128

Orin fún ìgòkè.

Ìbẹ̀rù Olúwa dára

128 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:
    tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀
Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ
    ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ
Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere
    eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;
    àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.
Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,
    tí ó bẹ̀rù Olúwa.

Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,
    kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre
Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.
    Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.
Láti àlàáfíà lára Israẹli.

Òwe 27

27 Má ṣe yangàn nítorí ọ̀la
    nítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé.

Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ
    àní àlejò, kí ó má sì ṣe ètè ìwọ fúnrarẹ̀.

Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwo
    ṣùgbọ́n ìbínú aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.

Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀
    ṣùgbọ́n ta ni ó le è dúró níwájú owú?

Ìbániwí gbangba sàn
    ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.

Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́,
    ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn.

Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó
    ṣùgbọ́n òróǹró gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.

Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀
    ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.

Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn
    bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó ṣàkóso.

10 Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀,
    má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdààmú dé bá ọ
    ó sàn kí o jẹ́ aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà sí ni.

11 Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi
    nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi.

12 Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́
    ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀.

13 Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjèjì
    fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oníṣekúṣe.

14 Bí ènìyàn kan ń kígbe súre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀
    a ó kà á sí bí èpè.

15 Àyà tí ó máa ń jà dàbí
    ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;
16 dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kun
    tàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.

17 Bí irin tí ń pọ́n irin mú
    bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.

18 Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èso rẹ̀
    ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.

19 Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò ó
    bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn.

20 Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí
    bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.

21 Iná fún fàdákà iná ìléru fún wúrà,
    ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà.

22 Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó,
    fi ọmọ odó gún un bí èlùbọ́
    ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.

23 Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà
    bojútó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;
24 Nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí
    adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.

25 Nígbà tí a bá kó koríko, ewéko tuntun yóò sì hù jáde, a ó sì kó koríko àwọn orí òkè wọlé
26 àwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ,
    àti ewúrẹ́ yóò pèsè owó oko.

27 Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà ewúrẹ́
    láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ
    àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.

Jakọbu 4:8-17

Ẹ súnmọ́ Ọlọ́run, òun ó sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀; ẹ sì ṣe ọkàn yín ní mímọ́, ẹ̀yin oníyèméjì. Ẹ banújẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, kí ẹ sì hu fún ẹkún. Ẹ jẹ́ kí ẹ̀rín yín kí ó di ọ̀fọ̀, àti ayọ̀ yín kí ó di ìbànújẹ́. 10 Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, òun ó sì gbé yín ga.

11 Ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ibi sí ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ibi sí arákùnrin rẹ̀, tí ó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ibi sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùfẹ́ òfin, bí kò ṣe onídàájọ́. 12 Aṣòfin àti onídàájọ́ kan ṣoṣo ní ó ń bẹ, àní ẹni tí ó lè gbàlà tí ó sì le parun, ṣùgbọ́n ta ni ìwọ tí ó ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́?

Má ṣe ìlérí nípa ọjọ́ ọ̀la

13 Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin tí ó ń wí pé, “Lónìí tàbí lọ́la àwa ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì ṣe ọdún kan níbẹ̀, a ó sì ṣòwò, a ó sì jèrè.” 14 Nígbà tí ẹ̀yin kò mọ ohun tí yóò hù lọ́la. Kí ni ẹ̀mí yín? Ìkùùkuu sá à ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ̀, lẹ́yìn náà a sì túká lọ. 15 Èyí tí ẹ̀ bá fi wí pé, “Bí Olúwa bá fẹ́, àwa yóò wà láààyè, àwa ó sì ṣe èyí tàbí èyí i nì.” 16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń gbéraga nínú ìfọ́nnu yín, gbogbo irú ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀, ibi ni. 17 Nítorí náà ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.