Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 1

ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ

Saamu 1–41

(A)Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
    tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
    tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
    àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
    tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
    Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
    Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
    tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
    ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

Òwe 30:1-10

Àwọn ọ̀rọ̀ tí Aguri sọ

30 Àwọn ọ̀rọ̀ Aguri ọmọ Jake, ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí ọkùnrin yìí sọ fún Itieli.

Sí Itieli àti sí Ukali.

“Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn;
    N kò ní òye ènìyàn.
Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́n
    tàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì
Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀?
    Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀?
Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ?
    Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀?
Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀?
    Sọ fún mi bí o bá mọ̀.

“Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù;
    òun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn
Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,
    àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́.

“Ohun méjì ni mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa;
    má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú:
Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi;
    má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀,
    ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan,
Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ
    kí ń sì wí pé, ‘Ta ni Olúwa?’
Tàbí kí ń di òtòṣì kí ń sì jalè
    kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.

10 “Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀,
    kí ó má ba fi ọ́ bú, kí ìwọ má ba jẹ̀bi.

1 Kọrinti 2:1-5

(A)Nígba tí èmí tọ̀ yín wá, ẹ̀yin ará, kì í ṣe nípa ọ̀rọ̀ gíga àti ọgbọ́n gíga ni mo fi bá yín sọ̀rọ̀, nígbà tí èmi ń sọ̀rọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run fún un yín. (B)Èmi ti pinnu láti má mọ ohunkóhun nígbà ti mo wà láàrín yín bí kò ṣe Jesu Kristi, ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. (C)Èmi sì tọ̀ yín wá ni àìlera, àti ní ẹ̀rù, àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwárìrì. (D)Ìwàásù mi àti ẹ̀kọ́ mi, kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn àti ọ̀rọ̀ tí a fi ń yí ènìyàn lọ́kàn padà, bí kò ṣe nípa ìfihàn agbára Ẹ̀mí. (E)Kí ìgbàgbọ́ yín kí ó má ṣe dúró lórí ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ó dúró lórí agbára Ọlọ́run.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.