Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 19

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

19 Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;
    Àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;
    wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.
Kò sí ohùn tàbí èdè
    níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn
(A)Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé,
    ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé.
Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.
    Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá,
    òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.
Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá
    àti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀;
    kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀.

Pípé ni òfin Olúwa,
    ó ń yí ọkàn padà.
Ẹ̀rí Olúwa dánilójú,
    ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
Ìlànà Olúwa tọ̀nà,
    ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.
Àṣẹ Olúwa ni mímọ́,
    ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.
Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́,
    ó ń faradà títí láéláé.
Ìdájọ́ Olúwa dájú
    òdodo ni gbogbo wọn.

10 Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ,
    ju wúrà tí o dára jùlọ,
wọ́n dùn ju oyin lọ,
    àti ju afárá oyin lọ.
11 Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí;
    nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.
12 Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀?
    Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.
13 Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;
    má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi.
Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin,
    èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

14 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi
    kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,
    Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.

Òwe 21:1-17

21 Ọkàn ọba ń bẹ lọ́wọ́ Olúwa;
    a máa darí rẹ̀ lọ ibi tí ó fẹ́ bí ipa omi.

Gbogbo ọ̀nà ènìyàn dàbí i pé ó dára lójú rẹ̀
    ṣùgbọ́n, Olúwa ló ń díwọ̀n ọkàn.

Ṣíṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà
    ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí Olúwa ju ẹbọ lọ.

Ojú tí ó gbéga àti ọkàn ìgbéraga,
    ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ẹ̀ṣẹ̀ ni!

Ètè àwọn olóye jásí èrè
    bí ìkánjú ṣe máa ń fa òsì kíákíá.

Ìṣúra tí a kójọ nípasẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́
    jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹ́kùn ikú.

Ìwà ipá àwọn ènìyàn búburú yóò wọ́ wọn lọ,
    nítorí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́.

Ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kún fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀
    ṣùgbọ́n iṣẹ́ onínú funfun jẹ́ títọ́.

Ó sàn láti máa gbé ní kọ̀rọ̀ orí òrùlé
    ju láti ṣe àjọpín ilé pẹ̀lú aya oníjà.

10 Ènìyàn búburú ń fẹ́ ibi
    aládùúgbò rẹ̀ kì í rí àánú kankan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.

11 Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn,
    òpè a máa kọ́gbọ́n,
    nígbà tí a bá sì kọ́ ọlọ́gbọ́n yóò ní ìmọ̀.

12 Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburú
    ó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun.

Ìṣúra ẹni tí o gbọ́n

13 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú,
    òun tìkára rẹ̀ yóò ké pẹ̀lú;
    ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́.

14 Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò:
    àti owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá,
    dẹ́kun ìbínú líle.

15 Ayọ̀ ni fún olódodo láti ṣe ìdájọ́:
    ṣùgbọ́n ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

16 Ẹni tí ó bá yà kúrò ní ọ̀nà òye,
    yóò máa gbé inú ìjọ àwọn òkú.

17 Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di tálákà:
    ẹni tí ó fẹ́ ọtí wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀.

Matiu 21:23-32

A béèrè àṣẹ tí Jesu ń lò

23 (A)Jesu wọ tẹmpili, nígbà tí ó ń kọ́ni, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù tọ̀ ọ́ wá. Wọ́n béèrè pé “nípa àṣẹ wo ni o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí?”

24 Jesu sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi yóò si bí yin léèrè ohun kan, bí ẹ̀yin bá lé sọ fún mi, nígbà náà èmi yóò sọ fún yín, àṣẹ tí Èmi fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí. 25 Níbo ni ìtẹ̀bọmi Johanu ti wa? Láti ọ̀run wá ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn.”

Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun yóò wí fún wa pé, ‘Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’ 26 (B)Ní ìdàkejì, bí àwa bá sì sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, àwa bẹ̀rù ìjọ ènìyàn, nítorí gbogbo wọ́n ka Johanu sí wòlíì.’ ”

27 Nítorí náà wọ́n sì dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”

Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí èyí, èmi kò ní sọ àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.

Òwe àwọn ọmọ méjì

28 (C)“Kí ni ẹ rò nípa eléyìí? Ọkùnrin kan ti ó ní àwọn ọmọkùnrin méjì. Ó sọ fún èyí ẹ̀gbọ́n pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí.’

29 “Ó sì dá baba rẹ̀ lóhùn pé, ‘Èmi kò ní í lọ,’ ṣùgbọ́n níkẹyìn ó yí ọkàn padà, ó sì lọ.

30 “Nígbà náà ni baba yìí tún sọ fún èyí àbúrò pé, ‘Lọ ṣiṣẹ́ ní oko.’ Ọmọ náà sì sọ pé, ‘Èmi yóò lọ, baba,’ ṣùgbọ́n kò lọ rárá.

31 “Nínú àwọn méjèèjì yìí, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba wọn?”

Gbogbo wọn sì fohùn ṣọ̀kan pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni.”

Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run síwájú yín. 32 Nítorí Johanu tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.