Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 19

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

19 Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;
    Àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;
    wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.
Kò sí ohùn tàbí èdè
    níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn
(A)Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé,
    ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé.
Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.
    Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá,
    òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.
Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá
    àti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀;
    kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀.

Pípé ni òfin Olúwa,
    ó ń yí ọkàn padà.
Ẹ̀rí Olúwa dánilójú,
    ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
Ìlànà Olúwa tọ̀nà,
    ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.
Àṣẹ Olúwa ni mímọ́,
    ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.
Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́,
    ó ń faradà títí láéláé.
Ìdájọ́ Olúwa dájú
    òdodo ni gbogbo wọn.

10 Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ,
    ju wúrà tí o dára jùlọ,
wọ́n dùn ju oyin lọ,
    àti ju afárá oyin lọ.
11 Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí;
    nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.
12 Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀?
    Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.
13 Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;
    má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi.
Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin,
    èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

14 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi
    kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,
    Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.

Òwe 15:1-17

15 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà
    ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.

Ahọ́n ọlọ́gbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jáde
    ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde.

Ojú Olúwa wà níbi gbogbo,
    Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.

Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè
    ṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run.

Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra,
    ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.

Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀;
    ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.

Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburú
    ṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ ẹ lọ́rùn.

Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú,
    ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.

10 Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an,
    ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.

11 Ikú àti ìparun ṣí sílẹ̀ níwájú Olúwa,
    mélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn.

12 Ẹlẹ́gàn kò fẹ́ ẹni tí ń ba wí:
    kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.

13 Inú dídùn máa ń mú kí ojú túká
    ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ọkàn máa ń pa ẹ̀mí run.

14 Ọkàn olóye ń wá ìmọ̀
    ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń fẹ́ ìwà òmùgọ̀ bí ẹní jẹun.

15 Gbogbo ọjọ́ àwọn olùpọ́njú jẹ́ ibi,
    ṣùgbọ́n onínúdídùn ń jẹ àlàáfíà ní ìgbà gbogbo.

16 Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù Olúwa sì wà
    ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu.

17 Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà
    sàn ju àbọ́pa màlúù tòun ti ìríra.

Heberu 11:17-22

17 (A)Nípa ìgbàgbọ́ ni Abrahamu, nígbà tí a dán an wò láti, fi Isaaki rú ẹbọ: àní òun ẹni tí ó rí ìlérí gba múra tan láti fi ọmọ bíbí rẹ kan ṣoṣo rú ẹbọ. 18 (B)Nípa ẹni tí wí pé, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀:” 19 Ó sì rò ó si pé Ọlọ́run tilẹ̀ lè gbé e dìde kúrò nínú òkú, bẹ́ẹ̀ ni, bí a bá sọ ọ́ lọ́nà àpẹẹrẹ, ó gbà á padà.

20 (C)Nípa ìgbàgbọ́ ní Isaaki súre fún Jakọbu àti Esau ní ti ohun tí ń bọ̀.

21 (D)Nípa ìgbàgbọ́ ni Jakọbu, nígbà tí o ń ku lọ, ó súre fún àwọn ọmọ Josẹfu ni ọ̀kọ̀ọ̀kan; ó sì sinmi ní ìtẹríba lé orí ọ̀pá rẹ̀.

22 (E)Nípa ìgbàgbọ́ ni Josẹfu, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Israẹli; ó sì pàṣẹ ní ti àwọn egungun rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.