Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
ÌWÉ KẸTA
Saamu 73–89
Saamu ti Asafu.
73 Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli,
fún àwọn ọlọ́kàn funfun.
2 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán;
ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.
3 Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé
nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.
4 Wọn kò ṣe wàhálà;
ara wọn mókun wọn sì lágbára.
5 Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn;
a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.
6 Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn;
ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.
7 Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá;
ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n
8 Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti
ìnilára, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.
9 Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run
ahọ́n wọn gba ipò ayé.
10 Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn
wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀?
Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?”
12 Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí
ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀.
13 Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́;
nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.
14 Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu;
a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.
15 Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,”
Èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.
16 Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí,
Ó jẹ́ ìnilára fún mi.
17 Títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run;
Nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.
18 Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́
ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.
19 Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí
bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!
Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá!
20 Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí,
bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa,
ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.
14 Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀,
ṣùgbọ́n aṣiwèrè obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ fà á lulẹ̀.
2 Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù Olúwa,
ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn Olúwa.
3 Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàṣán fún ẹ̀yìn rẹ̀,
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.
4 Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóní
ṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá.
5 Ẹlẹ́rìí tí ń ṣọ òtítọ́ kì í tan ni
ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde.
6 Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,
ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.
7 Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,
nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.
8 Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn
ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ.
9 Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀
ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere.
Ìwòsàn ọmọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù
14 (A)Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ ìjọ ènìyàn, ọkùnrin kan tọ̀ Jesu wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí pé, 15 “Olúwa, ṣàánú fún ọmọ mi, nítorí tí ó ní wárápá. Ó sì ń joró gidigidi, nígbà púpọ̀ ni ó máa ń ṣubú sínú iná tàbí sínú omi. 16 Mo sì ti mú un tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè wò ó sàn.”
17 Jesu sì dáhùn wí pé, “A! Ẹ̀yìn alágídí ọkàn àti aláìgbàgbọ́ ènìyàn, èmi yóò ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi ó sì ti fi ara dà á fún yín tó? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín yìí.” 18 Nígbà náà ni Jesu bá ẹ̀mí èṣù tí ó ń bẹ nínú ọmọkùnrin náà wí, ó sì fi í sílẹ̀, à mú ọmọkùnrin náà láradá láti ìgbà náà lọ.
19 (B)Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi Jesu níkọ̀kọ̀ pé, “Èéṣe tí àwa kò lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?”
20 (C)Jesu sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí hóró musitadi, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Sípò kúrò níhìn-ín yìí,’ òun yóò sì ṣí ipò. Kò sì ní sí ohun tí kò ní í ṣe é ṣe fún yín.” 21 Ṣùgbọ́n irú ẹ̀mí èṣù yìí kò ní lọ, bí kò ṣe nípa àwẹ̀ àti àdúrà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.