Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
9 Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọ
Ọlọ́run; lára ohun èlò orin
olókùn mẹ́wàá èmi yóò
kọ orin sí ọ
10 Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba,
ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára.
Lọ́wọ́ pípanirun. 11 Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì
tí ẹnu wọn kún fún èké,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.
12 Kí àwọn ọmọkùnrin wa
kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn,
àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé
tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.
13 Àká wa yóò kún
pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ
àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún,
ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:
14 Àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo
kí ó má sí ìkọlù,
kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn,
kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀,
Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà,
tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.
Olùfẹ́
2 Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí.
Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.
“Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi,
àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi
Orí mi kún fún omi ìrì,
irun mi kún fún òtútù òru.”
3 Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi
ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀?
Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi
ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?
4 Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ìlẹ̀kùn
inú mi sì yọ́ sí i
5 Èmi dìde láti ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,
òjìá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi,
òjìá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń sàn
sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn
6 Èmi ṣí ìlẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,
ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ
ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀.
Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i.
Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn
7 Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi
bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká.
Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́;
wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi.
Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!
8 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yín
bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi,
kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un?
Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi.
Ọ̀rẹ́
9 Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ,
ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?
Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ
tí ìwọ fi ń fi wá bú bẹ́ẹ̀?
Olùfẹ́
10 Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n
ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ.
11 Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọ
ìdì irun rẹ̀ rí bí i imọ̀ ọ̀pẹ
ó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò
12 Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà
ní ẹ̀bá odò tí ń sàn,
tí a fi wàrà wẹ̀,
tí ó jì, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́
13 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí
tí ó sun òórùn tùràrí dídùn
Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì
ó ń kán òjìá olóòórùn dídùn
14 Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà,
tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká
Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídán
tí a fi safire ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
15 Ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí i òpó mábù
tí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára
Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kedari Lebanoni,
tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́.
16 Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀
ó wu ni pátápátá.
Háà! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,
Èyí ni olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.
Ọ̀rẹ́
6 Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,
Ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?
Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,
kí a lè bá ọ wá a?
Olólùfẹ́
2 Olùfẹ́ mi ti sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀,
sí ibi ibùsùn tùràrí,
láti máa jẹ nínú ọgbà
láti kó ìtànná lílì jọ.
3 Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi,
Ó ń jẹ láàrín ìtànná lílì.
19 Nítorí pé èyí ní ìgbóríyìn fún, bí ènìyàn bá fi ara da ìrora, ìjìyà lọ́nà àìtọ́, nítorí ọkàn rere sí Ọlọ́run. 20 Ṣùgbọ́n ògo kín ni ó jẹ́, nígbà tí ẹ ba ṣẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á? Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá ń ṣe rere tí ẹ sì ń jìyà, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á, ẹ̀yín ní ọpẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. 21 Sí èyí ni a pè yín: nítorí Kristi pẹ̀lú jìyà fún un yin, ó fi àpẹẹrẹ sílẹ̀ fún un yín, kí ẹ̀yin lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀:
22 (A)“Òun kò dẹ́ṣẹ̀ kankan,
bẹ́ẹ̀ sì ni, a kò rí ẹ̀tàn kan lẹ́nu rẹ̀.”
23 Ẹni, nígbà tí a kẹ́gàn rẹ̀, tí kò sì padà kẹ́gàn; nígbà tí ó jìyà tí kò sì halẹ̀; ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹni ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́. 24 (B)Ẹni tí òun tìkára rẹ̀ fi ara rẹ̀ ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi àgbélébùú, pé kí àwa lè di òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ki a sì di ààyè sí òdodo: nípa ìjìyà ẹni tí ó mú yín láradá. 25 Nítorí tí ẹ̀yin ń ṣáko lọ bí àgùntàn, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin ti padà sí ọ̀dọ̀ olùṣọ́-àgùntàn àti bíṣọ́ọ̀bù ọkàn yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.