Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
84 Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun!
2 Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́
ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa
àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀
sí Ọlọ́run alààyè.
3 Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé,
ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀,
níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí:
ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.
4 Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ;
wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.
5 Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ
àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.
6 Àwọn tí ń la Àfonífojì omijé lọ
wọn sọ ọ́ di kànga
àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;
7 Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá
títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.
8 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára;
tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.
9 Wo asà wa, Ọlọ́run;
fi ojú àánú wò àwọn ẹni ààmì òróró rẹ.
10 Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ
ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ;
èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi
jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11 Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà;
Olúwa fún ni ní ojúrere àti ọlá;
kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn
fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.
12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Ọgbọ́n Solomoni
29 Ọlọ́run sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, àti òye ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, àti ìmọ̀ gbígbòòrò òye tí a kò le è fiwé iyanrìn tí ó wà létí Òkun. 30 Ọgbọ́n Solomoni sì pọ̀ ju ọgbọ́n ọkùnrin ìlà-oòrùn lọ, ó sì pọ̀ ju gbogbo ọgbọ́n Ejibiti lọ. 31 Ó sì ní òye ju gbogbo ènìyàn lọ, ju Etani, ará Esra, àti Hemani àti Kalkoli, àti Darda àwọn ọmọ Maholi lọ. Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè yíká. 32 Ó sì pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (3,000) òwe, àwọn orin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó-lé-márùn-ún (1,005). 33 Ó sì sọ̀rọ̀ ti igi, láti kedari tí ń bẹ ní Lebanoni dé Hísópù tí ń dàgbà lára ògiri. Ó sì tún sọ ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ, àti ohun tí ń rákò àti ti ẹja. 34 Àwọn ènìyàn sì ń wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọba ayé láti wá gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.
Ọjọ́ Olúwa fẹ́rẹ dé
11 (A)Àti èyí, bí ẹ̀yin ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsin yìí fún yín láti jí lójú orun: nítorí nísinsin yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ. 12 (B)Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀. 13 (C)Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara. 14 (D)Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.