Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 50:16-23

16 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú:

“Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ,
    tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?
17 Ìwọ kórìíra àṣẹ mi,
    ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.
18 Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́ ọn,
    ìwọ sì da ara rẹ dé àwọn alágbèrè.
19 Ìwọ lo ẹnu rẹ fún aburú,
    ìwọ sì ń fi ahọ́n rẹ pète ẹ̀tàn.
20 Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí arákùnrin rẹ,
    ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá rẹ jẹ́.
21 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́;
    ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ,
ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí,
    èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara rẹ.

22 “Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
    Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, láìsí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀.
23 Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe,
    kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”

2 Samuẹli 13:1-19

Amnoni àti Tamari

13 Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Absalomu ọmọ Dafidi ní àbúrò obìnrin kan tí ó ṣe arẹwà, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Tamari; Amnoni ọmọ Dafidi sì fẹ́ràn rẹ̀.

Amnoni sì banújẹ́ títí ó fi ṣe àìsàn nítorí Tamari àbúrò rẹ̀ obìnrin; nítorí pé wúńdíá ni; ó sì ṣe ohun tí ó ṣòro lójú Amnoni láti bá a dàpọ̀.

Ṣùgbọ́n Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea ẹ̀gbọ́n Dafidi: Jonadabu sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn gidigidi. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ ọmọ ọba ń fi ń rù lójoojúmọ́ báyìí? Ǹjẹ́ o kò ní sọ fún mi?”

Amnoni sì wí fún un pé, “Èmi fẹ́ Tamari àbúrò Absalomu arákùnrin mi.”

Jonadabu sì wí fún un pé, “Dùbúlẹ̀ ní ibùsùn rẹ kí ìwọ sì díbọ́n pé, ìwọ kò sàn: baba rẹ yóò sì wá wò ọ́, ìwọ ó sì wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Tamari àbúrò mi wá kí ó sì fún mi ní oúnjẹ kí ó sì ṣe oúnjẹ náà níwájú mi kí èmi ó rí i, èmi ó sì jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’ ”

Amnoni sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn: ọba sì wá wò ó, Amnoni sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀.”

Dafidi sì ránṣẹ́ sí Tamari ní ilé pé, “Lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ, kí ó sì se oúnjẹ fún un.” Tamari sì lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdùbúlẹ̀. Tamari sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà. Òun sì mú àwo náà, ó sì dà á sínú àwo mìíràn níwájú rẹ̀; ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti jẹ.

Amnoni sì wí pé, “Jẹ́ kí gbogbo ọkùnrin jáde kúrò lọ́dọ̀ mi!” Wọ́n sì jáde olúkúlùkù ọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 10 Amnoni sì wí fún Tamari pé, “Mú oúnjẹ náà wá sí yàrá, èmi ó sì jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ.” Tamari sì mú àkàrà tí ó ṣe, ó sì mú un tọ Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní yàrá. 11 Nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti fi oúnjẹ fún un, òun sì dìímú, ó sì wí fún un pé, “Wá dùbúlẹ̀ tì mí, àbúrò mi.”

12 Òun sì dá a lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀gbọ́n mi, má ṣe tẹ́ mi; nítorí pé kò tọ kí a ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Israẹli, ìwọ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí. 13 Àti èmi, níbo ni èmi ó gbé ìtìjú mi wọ̀? Ìwọ ó sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣiwèrè ní Israẹli. Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́, sọ fún ọba; nítorí pé òun kì yóò kọ̀ láti fi mí fún ọ.” 14 Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́ ohùn rẹ̀; ó sì fi agbára mú un, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì bá a dàpọ̀.

15 Amnoni sì kórìíra rẹ̀ gidigidi, ìríra náà sì wá ju ìfẹ́ tí òun ti ní sí i rí lọ. Amnoni sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ!”

16 Òun sì wí fún un pé, “Kó ha ní ìdí bí! Lílé tí ìwọ ń lé mi yìí burú ju èyí tí ìwọ ti ṣe sí mi lọ.”

Ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. 17 Òun sì pe ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, ti obìnrin yìí sóde fún mi, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.” 18 Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan lára rẹ̀: nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúńdíá máa ń wọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn. 19 Tamari sì bu eérú sí orí rẹ̀, ó sì fa aṣọ aláràbarà tí ń bẹ lára rẹ̀ ya, ó sì ká ọwọ́ rẹ̀ lé orí, ó sì ń kígbe bí ó ti ń lọ.

1 Kọrinti 12:27-31

27 (A)Gbogbo yín jẹ́ ara Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ara Kristi. 28 (B)Ọlọ́run sì gbé àwọn mìíràn kalẹ̀ nínú ìjọ, èkínní àwọn aposteli, èkejì àwọn wòlíì, ẹ̀kẹta àwọn olùkọ́ni, lẹ́yìn náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu, lẹ́yìn náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmúláradá, àwọn olùrànlọ́wọ́ àti àwọn agbani nímọ̀ràn, àwọn tí ń sọ onírúurú èdè. 29 Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ aposteli bi? Tàbí gbogbo ènìyàn ni wòlíì bí? Ṣe gbogbo ènìyàn ní olùkọ́ni? Ṣé gbogbo ènìyàn ló ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bí? 30 Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí? Rárá. Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Ọlọ́run fún ní ẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí? Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ́n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí? 31 Ṣùgbọ́n, ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn ti ó tóbi jù.

Síbẹ̀ èmi o fi ọ̀nà kan tí ó tayọ rékọjá hàn yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.