Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ti Dafidi. Saamu.
24 (A)Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,
ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;
2 Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí Òkun
ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.
3 Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?
Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
4 (B)Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,
ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán
tí kò sì búra èké.
5 Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,
àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.
6 Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,
tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.
7 Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà;
Kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé!
Kí ọba ògo le è wọlé.
8 Ta ni ọba ògo náà?
Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le,
Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.
9 Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà;
kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
kí Ọba ògo le è wọlé wá.
10 Ta ni Ọba ògo náà?
Olúwa àwọn ọmọ-ogun
Òun ni Ọba ògo náà. Sela.
Àpótí náà
37 (A)Besaleli sì fi igi ṣittimu ṣe àpótí náà, ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀. 2 Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó ní inú àti ní òde, ó sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká. 3 Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún, láti fi wọ́n sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ẹsẹ̀ rẹ̀, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì. 4 Ó sì fi igi kasia ṣe ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n. 5 Ó sì fi ọ̀pá náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà láti fi gbé e.
6 Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀. 7 Ó sì ṣe kérúbù méjì láti inú wúrà tí a fi òòlù sí igun ìtẹ́ àánú náà. 8 Ó ṣe kérúbù kan ní igun kìn-ín-ní, àti kérúbù kejì sí igun kejì; kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì pẹ̀lú ìbòrí wọn. 9 Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè, tí wọn yóò sì fi ìyẹ́ apá wọn ṣe ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú. Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́.
Tábìlì náà
10 (B)Ó ṣe tábìlì igi ṣittimu ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga. 11 Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká. 12 Ó sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká. 13 Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 14 Ní abẹ́ ìgbátí náà ni àwọn òrùka náà yóò wà, ààyè láti máa fi gbé tábìlì náà. 15 Ó sì fi igi kasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n, láti máa fi wọ́n gbé tábìlì náà. 16 Ó sì ṣe àwọn ohun èlò tí ó wà lórí tábìlì náà ní ojúlówó wúrà, abọ́ rẹ̀, àwo rẹ, àwokòtò rẹ̀ àti ìgò rẹ̀ fún dída ọrẹ mímu jáde.
Àwọn ìlànà fún ìjọ
2 Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́; 3 Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣí ìlẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kristi, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú: 4 Ẹ gbàdúrà pé kí èmi le è máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi. 5 (A)Ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ sì máa ṣe ṣí àǹfààní tí ẹ bá nílò. 6 Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.
Àwọn ìkíni ìkẹyìn
7 (B)Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikiku yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòtítọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa: 8 Ẹni tí èmí ń rán sí yín nítorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọkàn yín nínú; 9 (C)Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Onesimu, arákùnrin olóòtítọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín. Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín-yìí fún un yín.
10 (D)Aristarku, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Marku, ọmọ arábìnrin Barnaba (Nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ti gba àṣẹ; bí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ gbà á).
11 Àti Jesu, ẹni tí à ń pè ní Justu, ẹni tí ń ṣe ti àwọn onílà. Àwọn wọ̀nyí nìkan ni olùbáṣiṣẹ́ mí fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn ẹni tí ó tí jásí ìtùnú fún mi.
12 Epafira, ẹni tí ń ṣe ọ̀kan nínú yín àti ìránṣẹ́ Kristi Jesu kí i yín. Òun fi ìwàyáàjà gbàdúrà nígbà gbogbo fún un yín, kí ẹ̀yin kí ó lè dúró ní pípé nínú ohun gbogbo nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. 13 Nítorí mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ń ṣiṣẹ́ kárakára fún yín, àti fún àwọn tí ó wà ní Laodikea, àti àwọn tí ó wà ní Hirapoli.
14 (E)Luku, arákùnrin wa ọ̀wọ́n, oníṣègùn, àti Dema ki í yín.
15 Ẹ kí àwọn ará tí ó wà ní Laodikea, àti Nimpa, àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀.
16 Nígbà tí a bá sì ka ìwé yìí ní àárín yín tan, kí ẹ mú kí a kà á pẹ̀lú nínú ìjọ Laodikea; ẹ̀yin pẹ̀lú sì ka èyí tí ó ti Laodikea wá.
17 Kí ẹ sì wí fún Arkippu pe, “Kíyèsi iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ìwọ ti gbà nínú Olúwa kí o sì ṣe é ní kíkún.”
18 (F)Ìkíni láti ọwọ́ èmi Paulu. Ẹ máa rántí ìdè mi. Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹ̀lú yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.