Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 48

Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.

48 Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn
    ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.

(A)Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀,
    ayọ̀ gbogbo ayé
òkè Sioni, ní ìhà àríwá
    ní ìlú ọba ńlá.
Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀;
    ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.

Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀,
    wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.
Wọn rí i bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n
    a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ
Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀,
    ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.
Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi,
    wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,
    Bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,
Ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    ní ìlú Ọlọ́run wa,
    Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela.

Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run,
    àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
10 Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run,
    ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé,
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.
11 Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀
    kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn
    nítorí ìdájọ́ rẹ.

12 Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀,
    ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.
13 Kíyèsi odi rẹ̀,
    kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀
kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.

14 Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé,
    Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.

2 Samuẹli 3:1-12

Abneri àti Iṣboṣeti jà

Ogun náà sì pẹ́ títí láàrín ìdílé Saulu àti ìdílé Dafidi: agbára Dafidi sì ń pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n ìdílé Saulu ń rẹ̀yìn sí i.

(A)Dafidi sì bí ọmọkùnrin ní Hebroni:

Amnoni ni àkọ́bí rẹ̀ tí Ahinoamu ará Jesreeli bí fún un.

Èkejì rẹ̀ sì ni Kileabu, tí Abigaili aya Nabali ará Karmeli bí fún un;

ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ tí Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un.

Ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;

àti ẹ̀karùnún ni Ṣefatia ọmọ Abitali;

Ẹ̀kẹfà sì ni Itreamu, tí Egla aya Dafidi bí fún un.

Wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni.

Ó sì ṣe, nígbà tí ogun wà láàrín ìdílé Saulu àti ìdílé Dafidi, Abneri sì dì alágbára ní ìdílé Saulu. Saulu ti ní àlè kan, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Rispa, ọmọbìnrin Aiah: Iṣboṣeti sì bi Abneri léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi wọlé tọ àlè baba mi lọ.”

Abneri sì bínú gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti Iṣboṣeti sọ fún un, ó sì wí pé, “Èmi jẹ́ bí orí ajá ti Juda bí? Di òní yìí ni mo ṣàánú fún ìdílé Saulu baba rẹ, àti fún àwọn arákùnrin rẹ̀, àti fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí èmi kò sì fi ọ́ lé Dafidi lọ́wọ́, ìwọ sì kà ẹ̀ṣẹ̀ sí mí lọ́rùn nítorí obìnrin yìí lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe Abneri, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí Olúwa ti búra fún Dafidi, bí èmi kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ fún un. 10 Láti mú ìjọba náà kúrò ní ìdílé Saulu, àti láti gbé ìtẹ́ Dafidi kalẹ̀ lórí Israẹli, àti lórí Juda, láti Dani títí ó fi dé Beerṣeba.” 11 Òun kò sì lè dá Abneri lóhùn kan nítorí tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12 Abneri sì rán àwọn oníṣẹ́ sí Dafidi nítorí rẹ̀ wí pé, “Ti ta ni ilẹ̀ náà ń ṣe? Bá mi ṣe àdéhùn, èmi yóò si kó gbogbo Israẹli tọ̀ ọ́ wá.”

2 Kọrinti 10:7-11

(A)Ẹ̀yin sì ń wo nǹkan gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fihàn lóde. Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìgboyà nínú ara rẹ̀, ti Kristi ni òun, kí ó tún rò lẹ́ẹ̀kan si pé, bí òun ti jẹ́ ti Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwa pẹ̀lú jẹ́ ti Kristi. Nítorí bí mo tilẹ̀ ń ṣògo bí ó ti wù mi nítorí agbára, tí Olúwa ti fi fún wá fún ìdàgbàsókè, dípò fífà yín ṣubú, ojú kí yóò tì mí. Kí ó má ṣe dàbí ẹni pé èmi ń fi ìwé kíkọ dẹ́rùbà yín. 10 (B)Nítorí wọ́n wí pé, “Ìwé rẹ wúwo, wọn sì lágbára; ṣùgbọ́n ní ti ara ìrísí rẹ̀ jẹ aláìlera, ọ̀rọ̀ rẹ kò níláárí.” 11 Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé, irú ẹni tí àwa jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ nípa ìwé kíkọ nígbà tí àwa kò sí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa sì jẹ́ nínú iṣẹ́ pẹ̀lú nígbà ti àwa bá wà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.