Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
12 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé;
ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.
13 Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni,
nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i;
àkókò náà ti dé.
14 Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ.
15 Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,
gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ.
16 Torí tí Olúwa yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀.
17 Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;
kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn.
18 Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀,
àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:
19 “Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá
láti ọ̀run wá ni ó bojú wo ayé,
20 Láti gbọ́ ìrora ará túbú, láti tú
àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”
21 Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ní Sioni
àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu.
22 Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti
ìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.
23 Ní ipa ọ̀nà mi, ó rẹ agbára mi sílẹ̀,
ó gé ọjọ́ mi kúrú.
24 Èmi sì wí pé;
“Ọlọ́run mi, má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.
25 (A)Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
26 Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà;
gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ.
Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn
wọn yóò sì di àpatì.
27 Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀,
ọdún rẹ kò sì ní òpin.
28 Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dúró ní iwájú rẹ pẹ́;
a ó sì fi ẹsẹ̀ irú-ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú rẹ.”
Obìnrin ará Ṣunemu gba ilẹ̀ rẹ̀ padà
8 Nísinsin yìí, Eliṣa wí fún obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin jí padà sáyé pé, “jáde lọ pẹ̀lú ìdílé rẹ kí o sì lọ dúró fún ìgbà díẹ̀ ní ibikíbi tí o bá le dúró sí, nítorí Olúwa ti pàṣẹ ìyàn ní ìlú tí yóò lò tó ọdún méje.” 2 Obìnrin náà tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ti sọ. Òun àti ìdílé rẹ̀ sí lọ, wọ́n sì ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àwọn ará Filistini fún ọdún méje.
3 Ní ẹ̀yìn ọdún méje ó sì padà wá láti ilẹ̀ àwọn ará Filistini ó sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba láti lọ bẹ̀ ẹ́ fún ilé àti ilẹ̀ rẹ̀. 4 Ọba sì ń sọ̀rọ̀ sí Gehasi, ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run pé, “Sọ fún mi nípa gbogbo ohun ńlá tí Eliṣa ti ṣe.” 5 Bí Gehasi ti ń sọ bí tí Eliṣa ṣe jí òkú di alààyè, obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tí Eliṣa ti dá padà sí ayé wá láti bẹ ọba fún ilé àti ilẹ̀ rẹ̀.
Gehasi sì wí pé, “Obìnrin náà nìyìí olúwa mi ọba, ọmọkùnrin rẹ náà nìyí tí Eliṣa ti jí dìde sí ayé.” 6 Ọba béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà nípa rẹ̀, ó sì sọ fún un.
Ó sì yan ìjòyè kan fún ún fún ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì wí fún un pé, “Ẹ fún un padà gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ tirẹ̀, àti pẹ̀lú gbogbo èrè ilé rẹ̀ fún ún láti ọjọ́ tí ó ti kúrò ní ìlú títí di àsìkò yìí.”
Ìjà láàrín Paulu àti Barnaba
36 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòókan, Paulu sì sọ fún Barnaba pé, “Jẹ́ kí a tún padà lọ bẹ àwọn arákùnrin wa wò, bí wọn ti ń ṣe sí ni ìlú gbogbo tí àwa ti wàásù ọ̀rọ̀ Olúwa.” 37 Barnaba sì pinnu rẹ̀ láti mú Johanu lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku. 38 Ṣùgbọ́n Paulu rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni pamfilia, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà. 39 Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì: Barnaba sì mu Marku ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Saipurọsi. 40 Ṣùgbọ́n Paulu yan Sila, ó sì lọ, bí a ti fi lé oore-ọ̀fẹ́ Olúwa lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin. 41 Ó sì la Siria àti Kilikia lọ, ó ń mú ìjọ ní ọkàn le.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.