Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 102:12-28

12 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé;
    ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.
13 Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni,
    nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i;
    àkókò náà ti dé.
14 Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
    wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ.
15 Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,
    gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ.
16 Torí tí Olúwa yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀.
17 Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;
    kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn.

18 Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀,
    àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:
19 Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá
    láti ọ̀run wá ni ó bojú wo ayé,
20 Láti gbọ́ ìrora ará túbú, láti tú
    àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”
21 Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ní Sioni
    àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu.
22 Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti
    ìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.

23 Ní ipa ọ̀nà mi, ó rẹ agbára mi sílẹ̀,
    ó gé ọjọ́ mi kúrú.
24 Èmi sì wí pé;
    “Ọlọ́run mi, má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.
25 (A)Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
    ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
26 Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà;
    gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ.
Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn
    wọn yóò sì di àpatì.
27 Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀,
    ọdún rẹ kò sì ní òpin.
28 Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dúró ní iwájú rẹ pẹ́;
    a ó sì fi ẹsẹ̀ irú-ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú rẹ.”

2 Ọba 4:8-17

Ọmọ arábìnrin kan ará Ṣunemu jí dìde sáyé

Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu. Obìnrin ọlọ́rọ̀ kan sì wà níbẹ̀, ẹni tí ó rọ̀ ọ́ kí ó dúró jẹun. Bẹ́ẹ̀ ni nígbàkúgbà tí ó bá ń kọjá lọ, ó máa ń dúró níbẹ̀ láti jẹun. Ó sọ fún ọkọ rẹ̀, “Mo mọ̀ pé ọkùnrin tí ó máa ń sábà wá sí ọ̀dọ̀ wa jẹ́ ọkùnrin mímọ́ Ọlọ́run. 10 Jẹ́ kí a ṣe yàrá kékeré kan sórí ilé kí a sì gbé ibùsùn àti tábìlì oúnjẹ, àga kan àti fìtílà fún un. Nígbà náà ó lè dúró níbẹ̀ ní ìgbàkúgbà tí ó bá wá sọ́dọ̀ wa.”

11 Ní ọjọ́ kan nígbà tí Eliṣa wá, ó lọ sí orí òkè ní yàrá rẹ̀ ó sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀. 12 Ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Gehasi pé, “Pe ará Ṣunemu.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é wá, ó sì dúró níwájú rẹ̀. 13 Eliṣa wí fún un pé, “wí fún un, ‘Ìwọ ti lọ ṣe gbogbo àníyàn iṣẹ́ ìhìnrere fún wa. Nísinsin yìí kí ni a lè ṣe fún ọ?’ ”

“Ṣé a lè jẹ́ agbẹnusọ fún ọ ní ọ̀dọ̀ ọba tàbí olórí ogun?”

14 “Kí ni a lè ṣe fún obìnrin yìí?” Eliṣa béèrè.

Gehasi wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kò ní ọmọ, ọkọ rẹ̀ náà sì tún di arúgbó.”

15 Nígbà náà Eliṣa wí pé, “Pè é,” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é, ó sì dúró ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà. 16 Eliṣa sọ wí pé, “Ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, ìwọ yóò fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọ.”

“Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa mi!” n kò fi ara mọ́ ọn. “Jọ̀wọ́, ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, ma ṣe ṣi ìránṣẹ́ rẹ lọ́nà!”

17 Ṣùgbọ́n obìnrin náà lóyún ní ọdún kejì ní àkókò náà, ó bí ọmọ ọkùnrin kan, gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọ fún un.

2 Ọba 4:32-37

32 Nígbà tí Eliṣa dé inú ilé, níbẹ̀ ni òkú ọmọ ọkùnrin náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn. 33 Ó sì wọ ilé, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ àwọn méjèèjì ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 34 Nígbà náà ó dé orí ibùsùn, ó sùn sórí ọmọ ọkùnrin náà, ẹnu sí ẹnu, ojú sí ojú, ọwọ́ sí ọwọ́. Gẹ́gẹ́ bí ó ti nà ara rẹ̀ lórí rẹ̀, ara ọmọ náà sì gbóná. 35 Eliṣa yípadà lọ, ó sì rìn padà ó sì jáde wá sínú ilé nígbà náà ó sì padà sí orí ibùsùn ó sì tún nà lé e ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọmọ ọkùnrin náà sì sín ní ìgbà méje ó sì ṣí ojú rẹ̀.

36 Eliṣa sì pe Gehasi ó sì wí pé, “Pe ará Ṣunemu.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó dé, ó wí pé, “Gba ọmọ rẹ.” 37 Ó sì wọlé, ó sì kúnlẹ̀ síwájú ẹsẹ̀ rẹ̀ ó sì tẹ̀ Orí sílẹ̀. Nígbà náà ó sì mú ọmọ rẹ̀ ó sì jáde lọ.

Ìṣe àwọn Aposteli 14:1-7

Ní Ikoniomu

14 Ó sí ṣe, ni Ikoniomu, Paulu àti Barnaba jùmọ̀ wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti àwọn Helleni gbàgbọ́, Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbàgbọ́ Júù rú ọkàn àwọn aláìkọlà sókè, wọ́n sì mú wọn ni ọkàn ìkorò sí àwọn arákùnrin náà. Nítorí náà Paulu àti Barnaba gbé ibẹ̀ pẹ́, wọ́n ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú Olúwa, ẹni tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, ó sì mu kí iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu máa ti ọwọ́ wọn ṣe. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà pín sí méjì: apá kan dàpọ̀ mọ́ àwọn Júù, apá kan pẹ̀lú àwọn aposteli. Bí àwọn aláìkọlà, àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn olórí wọn ti fẹ́ kọlù wọ́n láti fi àbùkù kàn wọ́n, àti láti sọ wọ́n ní òkúta, wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì sálọ sí Lysra, àti Dabe, àwọn ìlú Likaonia àti sí agbègbè àyíká. Níbẹ̀ ni wọ́n sì ń wàásù ìhìnrere.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.