Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
21 Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀
ìwọ kò tí ì gbọ́?
A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá?
Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpìlẹ̀ ayé?
22 Òun jókòó lórí ìtẹ́ ní òkè òbírí ilẹ̀ ayé,
àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata.
Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà,
ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.
23 Ó sọ àwọn ọmọ ọba di asán
àti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo.
24 Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n,
kété tí a gbìn wọ́n,
kété tí wọ́n fi gbòǹgbò múlẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ,
bẹ́ ni ìjì líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò.
25 “Ta ni ẹ ó fi mi wé?
Tàbí ta ni ó bá mi dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́ wí.
26 Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo àwọn ọ̀run:
Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí?
Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan
tí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan.
Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀,
ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn kò sọnù.
27 Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu
àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli;
“Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa;
ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí
láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”?
28 Ìwọ kò tí ì mọ̀?
Ìwọ kò tí ì gbọ́?
Olúwa òun ni Ọlọ́run ayérayé,
Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé.
Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀,
àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀.
29 Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀
ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá.
30 Àní, ó ń rẹ̀ wọ́n àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ń rẹ̀wẹ̀sì,
àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú;
31 ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
yóò sọ agbára wọn di ọ̀tun.
Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì;
wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn,
wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.
147 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,
ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!
2 Olúwa kọ́ Jerusalẹmu;
Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.
3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn
ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀
ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ
5 Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára
òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
6 Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.
7 Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa
fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.
8 Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀
ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé
ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè
9 Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko
àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.
10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin
bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin
11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.
20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀
wọn ko mọ òfin rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
16 Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìhìnrere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa ṣògo lè. Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìhìnrere. 17 (A)Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, mo ní èrè kan, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe tinútinú mi, a ti fi iṣẹ́ ìríjú lé mi lọ́wọ́. 18 (B)Ní irú ipò báyìí, kín ni ẹ rò pé yóò jẹ èrè mi ni láti jẹ́? Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìhìnrere láìgba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.
19 Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i. 20 (C)Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn ba à lè tẹ́tí sí ìwàásù ìhìnrere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kristi. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí lábẹ́ òfin), kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin. 21 (D)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kristi), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin. 22 (E)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi ba à lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí. 23 Èmi sì ń ṣe ohun gbogbo nítorí ti ìhìnrere, kí èmi kí ó lè jẹ́ alábápín nínú rẹ̀ pẹ̀lú yín.
Jesu mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá
29 (A)Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú Sinagọgu, wọ́n lọ pẹ̀lú Jakọbu àti Johanu sí ilé Simoni àti Anderu. 30 Ìyá ìyàwó Simoni tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jesu nípa rẹ̀. 31 Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójúkan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
32 (B)Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí oòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá. 33 Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà. 34 Jesu sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú ààrùn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í ṣe.
Jesu ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láti gbàdúrà
35 (C)Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu nìkan jáde lọ sí aginjù kan, láti lọ gbàdúrà. 36 Simoni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a. 37 Nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!”
38 Jesu sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.” 39 (D)Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbègbè Galili, ó ń wàásù nínú Sinagọgu. Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.