Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 85:1-2

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

85 Ìwọ fi ojúrere hàn fún ilé rẹ, Olúwa;
    ìwọ mú ohun ìní Jakọbu bọ̀ sí ipò.
Ìwọ dárí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn rẹ jì
    ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Sela.

Saamu 85:8-13

Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí;
    ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀:
Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.
Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.

10 Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀;
    òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.
11 Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá
    òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.
12 Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́,
    ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde.
13 Òdodo síwájú rẹ lọ
    o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Hosea 6:1-6

Àìronúpìwàdà Israẹli

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa
ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
    ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá
Ó ti pa wá lára
    ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.
Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí
    ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò
    kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀
Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa
    Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n.
Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,
    Yóò jáde;
Yóò tọ̀ wá wá bí òjò
    bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”

“Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu?
    Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda?
Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀
    bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.
Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì.
    Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi
    Ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín
(A)Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;
    àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.

1 Tẹsalonika 1:2-10

Ọpẹ́ fún ìgbàgbọ́ àwọn ará Tẹsalonika

(A)Gbogbo ìgbà ni a máa ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítorí yín, a sì ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo pẹ̀lú. (B)A ń rántí yin ni àìsimi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Baba nípa iṣẹ́ ìgbàgbọ́ yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró ṣinṣin ìrètí yín nínú Jesu Kristi Olúwa wa.

(C)Àwa mọ̀ dájúdájú, ẹ̀yin olùfẹ́ wa, wí pé Ọlọ́run ti yàn yín fẹ́ fún ara rẹ̀. (D)Nítorí pé, nígbà tí a mú ìhìnrere tọ̀ yín wà, kò rí bí ọ̀rọ̀ lásán tí kò ní ìtumọ̀ sí i yín, bí kò ṣe pẹ̀lú agbára, pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, pẹ̀lú ìdánilójú tó jinlẹ̀. Bí ẹ̀yin ti mọ irú ènìyàn tí àwa jẹ́ láàrín yín nítorí yín. (E)Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá di aláwòkọ́ṣe wa àti ti Olúwa, ìdí ni pé, ẹ gba ẹ̀rí náà láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, ó mú wàhálà àti ìbànújẹ́ wá fún yín. (F)Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá fi di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onígbàgbọ́ tó wà ní agbègbè Makedonia àti Akaia. (G)Ọ̀rọ̀ Olúwa ti gbilẹ̀ níbi gbogbo láti ọ̀dọ̀ yín láti agbègbè Makedonia àti Akaia lọ, ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run tàn káàkiri. Nítorí náà, a kò ni láti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún wọn nípa rẹ̀. Ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i ròyìn fún wa bí ẹ ti gbà wá lálejò. Wọ́n ròyìn fún wa pẹ̀lú pé, ẹ ti yípadà kúrò nínú ìbọ̀rìṣà àti wí pé Ọlọ́run alààyè àti òtítọ́ nìkan ṣoṣo ni ẹ ń sìn, 10 (H)àti láti fi ojú ṣọ́nà fún ìpadàbọ̀ Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run wá, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú, Jesu, ẹni tí ó gbà wá lọ́wọ́ ìbínú tí ń bọ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.