Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
97 Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀
jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn
2 Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká
òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.
3 Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri
4 Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé
ayé rí i ó sì wárìrì
5 Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa,
níwájú Olúwa gbogbo ayé.
6 Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀.
7 (A)Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì,
àwọn tí ń fi ère gbéraga,
ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run!
8 Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn
inú àwọn ilé Juda sì dùn
Nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa
9 Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ
ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.
10 Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́
Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́
ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11 Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo
àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn
12 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo,
kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.
15 Mose sì yípadà, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú òkúta wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n kọ ìwé síhà méjèèjì, iwájú àti ẹ̀yin. 16 Iṣẹ́ Ọlọ́run sì ni wàláà náà; ìkọ̀wé náà jẹ́ ìkọ̀wé Ọlọ́run, a fín in sára àwọn òkúta wàláà náà.
17 Nígbà tí Joṣua gbọ́ ariwo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kígbe, ó sọ fún Mose pé, “Ariwo ogun wà nínú àgọ́.”
18 Mose dáhùn pé:
“Kì í ṣe ariwo fún ìṣẹ́gun,
kì í ṣe ariwo fún aṣẹ́gun;
ohùn àwọn tí ń kọrin ni mo gbọ́.”
19 Nígbà tí Mose dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì sọ wàláà ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ ní ìsàlẹ̀ òkè náà. 20 Ó sì gbé ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n ṣe, ó sì fi iná jó wọn; ó sì lọ̀ wọ́n kúnná, ó dà á sínú omi, ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli mu ún.
21 Mose sọ fún Aaroni pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe sí ọ, tí ìwọ ṣe mú wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí?”
22 Aaroni dáhùn wí pé, “Má ṣe bínú olúwa mi. Ìwọ mọ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe burú tó. 23 (A)Wọ́n sọ fún mi pé, ‘Ṣe òrìṣà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa. Bí ó ṣe ti Mose ẹni tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá àwa kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.’ 24 Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní òrùka wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Nígbà náà ni wọ́n fún mi ní wúrà, mo sì jù ú sínú iná, a sì fi ṣe ẹgbọrọ màlúù yìí!”
25 Mose rí pé àwọn ènìyàn náà kò ṣe ṣàkóso àti pé Aaroni ti sọ wọ́n di aláìlákóṣo láàrín àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn. 26 Bẹ́ẹ̀ ni Mose dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún Olúwa, kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ará Lefi sì péjọ yí i ká.
27 Nígbà náà ni ó sọ fún wọn pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, wí pé: ‘Kí olúkúlùkù ọkùnrin kí ó kọ idà rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ẹ lọ padà, kí ẹ jà láti àgọ́ kan dé òmíràn, olúkúlùkù kí ó pa arákùnrin rẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti aládùúgbò rẹ.’ ” 28 Àwọn ará Lefi ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ṣe pàṣẹ, àti ní ọjọ́ náà àwọn tí ó kú tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ènìyàn. 29 Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún Olúwa lónìí, nítorí ìwọ ti dìde sí àwọn ọmọ rẹ àti arákùnrin rẹ, ó sì ti bùkún fún ọ lónìí.”
30 Ní ọjọ́ kejì Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ̀yin ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi yóò gòkè lọ bá Olúwa; bóyá èmi lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.”
31 Bẹ́ẹ̀ ni Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìṣà wúrà fún ara wọn. 32 (B)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n ṣùgbọ́n tí kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, pa orúkọ mi rẹ́ kúrò nínú ìwé tí ìwọ ti kọ.”
33 Olúwa dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi, èmi yóò pa á rẹ́ kúrò nínú ìwé mi. 34 Ǹjẹ́ nísinsin yìí lọ, máa darí àwọn ènìyàn yìí lọ sí ibi ti mo sọ, angẹli mi yóò sì máa lọ ṣáájú yín. Ìgbà ń bọ̀ fún mi tì èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò, èmi yóò fi yà jẹ wọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
35 Olúwa sì yọ àwọn ènìyàn náà lẹ́nu, pẹ̀lú ààrùn nítorí ohun tí wọ́n ṣe ní ti ẹgbọrọ màlúù tí Aaroni ṣe.
Ìpè fún ìdúró ṣinṣin
17 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti sọ ṣáájú láti ọwọ́ àwọn aposteli Olúwa wa Jesu Kristi. 18 (A)Bí wọn ti wí fún yín pé, “Nígbà ìkẹyìn àwọn ẹlẹ́gàn yóò wà, tí wọn yóò máa rìn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run ti ara wọn.” 19 Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn ẹni tí ń ya ara wọn sí ọ̀tọ̀, àwọn ẹni ti ara, tí wọn kò ni Ẹ̀mí.
20 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́, ti ẹ ń gbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín tí ó mọ́ jùlọ, ti ẹ ń gbàdúrà nínú Ẹ̀mí Mímọ́. 21 Ẹ máa pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ̀yin ti ń retí àánú Olúwa wa Jesu Kristi tí yóò mú yín dé ìyè àìnípẹ̀kun.
22 Ẹ máa ṣàánú fún àwọn tí ń ṣe iyèméjì. 23 (B)Ẹ máa gba àwọn ẹlòmíràn là, nípa fífà wọ́n yọ kúrò nínú iná; kí ẹ sì máa ṣàánú pẹ̀lú ìbẹ̀rù kí ẹ sì kórìíra ẹ̀wù tí ara ti sọ di èérí.
Orin ìyìn sí Ọlọ́run
24 Ǹjẹ́ mo fi yín lé ẹni tí o lè pa yín mọ́ kúrò nínú ìkọ̀sẹ̀, tí o sì lè mú yín wá síwájú ògo rẹ̀ láìlábùkù pẹ̀lú ayọ̀ ńlá lọ́wọ́— 25 tí Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n nìkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa, ní ògo àti ọláńlá, ìjọba àti agbára, nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, kí gbogbo ayé tó wà, nísinsin yìí àti títí láéláé! Àmín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.