Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ìgbàlà láti inú òfin Ọlọ́run
41 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa,
ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ;
42 Nígbà náà ni èmi yóò dá
ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,
nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi
nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ
44 Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo
láé àti láéláé.
45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,
nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
46 Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba
ojú kì yóò sì tì mí,
47 Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ
nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
48 Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,
èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.
Abrahamu bẹ Olúwa nítorí Sodomu
16 Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, wọn kọjú sí ọ̀nà Sodomu, Abrahamu sì sìn wọ́n dé ọ̀nà. 17 Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ǹjẹ́ èmi yóò ha pa ohun tí mo fẹ́ ṣe mọ́ fún Abrahamu bí? 18 (A)Dájúdájú Abrahamu yóò sá à di orílẹ̀-èdè ńlá àti alágbára, àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni a ó bùkún fún nípasẹ̀ rẹ̀. 19 Nítorí tí èmi ti yàn án láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ará ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, láti máa pa ọ̀nà Olúwa mọ nípa ṣíṣe olóòtítọ́ àti olódodo: kí Olúwa le è mú ìlérí rẹ̀ fún Abrahamu ṣẹ.”
20 Olúwa sì wí pé, igbe Sodomu àti Gomorra pọ̀ púpọ̀ àti pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jọjọ. 21 “Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ síbẹ̀ láti ṣe ìwádìí igbe tí ó dé sí etí ìgbọ́ mi nípa wọn, kí èmi sì mọ òtítọ́ tí ó wà níbẹ̀.”
22 Àwọn ọkùnrin náà yí padà, wọ́n sì ń lọ sí ìhà Sodomu. Ṣùgbọ́n Abrahamu dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa. 23 Nígbà náà ni Abrahamu súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì wí pé, “Ìwọ yóò ha pa olódodo ènìyàn àti ènìyàn búburú run papọ̀ bí?” 24 “Bí ó bá ṣe pé Ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, Ìwọ yóò ha run ún, Ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà? 25 Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú Ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú, Ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tọ́ bi?”
26 Olúwa wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta (50) olódodo ní ìlú Sodomu, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tiwọn.”
27 Abrahamu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Wò ó nísinsin yìí, níwọ̀n bí èmi ti ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa, èmi ẹni tí í ṣe erùpẹ̀ àti eérú, 28 bí ó bá ṣe pe olódodo márùn-dínláàádọ́ta (45) ni ó wà nínú ìlú, Ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?”
Olúwa dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùn-dínláàádọ́ta nínú rẹ̀.”
29 Òun sì tún wí lẹ́ẹ̀kan si pé, “Bí ó bá ṣe pé ogójì (40) ni ńkọ́?”
Olúwa sì tún wí pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo ogójì nínú rẹ̀.”
30 Abrahamu sì tún bẹ Olúwa pé, “Kí Olúwa má ṣe bínú, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ̀rọ̀. Bí ó bá ṣe pé ọgbọ̀n (30) ni a rí níbẹ̀ ńkọ́?”
Olúwa dáhùn pé, “Bí mó bá rí ọgbọ̀n, Èmi kì yóò pa ìlú run.”
31 Abrahamu wí pé, “Níwọ́n bí mo ti ní ìgboyà láti bá Olúwa sọ̀rọ̀ báyìí, jẹ́ kí n tẹ̀síwájú. Bí o bá ṣe pé olódodo ogún péré ni ó wà nínú ìlú náà ńkọ́?”
Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa á run nítorí ogún ènìyàn náà.”
32 Abrahamu sì wí pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú Olúwa. Jẹ́ kí ń béèrè lẹ́ẹ̀kan si. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn mẹ́wàá ni ó jẹ́ olódodo ńkọ́?”
Olúwa wí pé, “Nítorí ènìyàn mẹ́wàá náà, Èmi kì yóò pa á run.”
33 Olúwa sì bá tirẹ̀ lọ, nígbà tí ó bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, Abrahamu sì padà sílé.
Olúwa ọjọ́ ìsinmi
12 (A)(B) Ní àkókò náà ni Jesu ń la àárín oko ọkà kan lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ebi sì ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i ya orí ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́. 2 Nígbà tí àwọn Farisi rí èyí. Wọ́n wí fún pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi.”
3 (C)Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò ha ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa á àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 4 Ó wọ inú ilé Ọlọ́run, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àkàrà tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí kò yẹ fún wọn láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan. 5 Tàbí ẹ̀yin kò ti kà á nínú òfin pé ní ọjọ́ ìsinmi, àwọn àlùfáà tí ó wà ní tẹmpili ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ tí wọ́n sì wà láìjẹ̀bi. 6 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, ẹni tí ó pọ̀ ju tẹmpili lọ wà níhìn-ín. 7 Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí, ‘Àánú ni èmi ń fẹ́ kì í ṣe ẹbọ,’ ẹ̀yin kì bá tí dá aláìlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi. 8 Nítorí pé Ọmọ Ènìyàn jẹ́ Olúwa ọjọ́ ìsinmi.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.