Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Saamu ti Dafidi.
8 Olúwa, Olúwa wa,
orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga
ju àwọn ọ̀run lọ.
2 (A)Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú
ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ,
láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
3 Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ,
iṣẹ́ ìka rẹ,
òṣùpá àti ìràwọ̀,
tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
4 kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀,
àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?
5 Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ,
ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.
6 Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;
ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
7 àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù,
àti ẹranko igbó,
8 ẹyẹ ojú ọrun,
àti ẹja inú Òkun,
àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun.
9 Olúwa, Olúwa wa,
Orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
22 “Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì òjò lọ rí bí,
ìwọ sì rí ilé ìṣúra yìnyín rí,
23 Tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu,
dé ọjọ́ ogun àti ìjà?
24 Ọ̀nà wo ni ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ń la,
tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?
25 Ta ni ó la ipadò fún ẹ̀kún omi,
àti ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
26 láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tí ènìyàn kò sí,
ní aginjù níbi tí ènìyàn kò sí;
27 láti mú ilẹ̀ tútù, ijù àti aláìro
láti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde?
28 Òjò ha ní baba bí?
Tàbí ta ni o bí ìkún ìṣe ìrì?
29 Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá?
Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run?
30 Nígbà tí omi di líle bí òkúta,
nígbà tí ojú ibú ńlá sì dìpọ̀.
31 “Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Pleiadesi dáradára?
Tàbí ìwọ le tún di Ìràwọ̀ Orioni?
32 Ìwọ le mú àwọn ààmì méjìlá ìràwọ̀ Masaroti jáde wá nígbà àkókò wọn?
Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Beari pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?
33 Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run?
Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?
34 “Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè dé àwọsánmọ̀
kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́?
35 Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kí ó le lọ,
ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ó sì wí fún wọn pé, ‘àwa nìyí’?
36 Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí odò ikùn
tàbí tí ó fi òye sínú àyà?
37 Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmọ̀?
Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde,
38 Nígbà tí erùpẹ̀ di líle,
àti ògúlùtu dìpọ̀?
Jesu ṣe ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́
15 (A)“Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́. 16 (B)Nígbà náà èmi yóò wá béèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé 17 Òun ni Ẹ̀mí òtítọ́. Ayé kò le gbà á. Nítorí ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí. Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí. Òun náà ti wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.