Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ọlọ́run ni ìpín wa
57 Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa:
èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
58 Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
59 Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi
èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.
60 Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra
láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
61 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,
èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
62 Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ
nítorí òfin òdodo rẹ.
63 Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ.
64 Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ Olúwa
Kọ́ mi ní òfin rẹ.
27 Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ,
nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.
28 Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé,
“Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,”
nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.
29 Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ,
ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.
30 Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí,
nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.
31 Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan
tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
32 Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyídáyidà
ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.
33 Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo.
34 (A)Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́,
ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀.
35 Ọlọ́gbọ́n jogún iyì,
ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.
Ọlọ́rọ̀ alákòóso
18 (A)(B) Ìjòyè kan sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, wí pé, “Olùkọ́ rere, kín ni èmi ó ṣe tí èmi ó fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”
19 Jesu wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí bí kò ṣe ẹnìkan, èyí sì ni Ọlọ́run. 20 (C)Ìwọ mọ̀ àwọn òfin: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ ”
21 Ó sì wí pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti pamọ́ láti ìgbà èwe mi wá.”
22 (D)Nígbà tí Jesu sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn tálákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra ní ọ̀run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
23 Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi: nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. 24 (E)Nígbà tí Jesu rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, ó wí pé, “Yóò ti ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run! 25 Nítorí ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run lọ.”
26 Àwọn tí ó sì gbọ́ wí pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha lè là?”
27 (F)Ó sì wí pé, “Ohun tí ó ṣòro lọ́dọ̀ ènìyàn kò ṣòro lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
28 (G)Peteru sì wí pé, “Sá wò ó, àwa ti fi ilé wa sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!”
29 Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run, 30 Tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.