Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:57-64

Ọlọ́run ni ìpín wa

57 Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa:
    èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
58 Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
    fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
59 Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi
    èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.
60 Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra
    láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
61 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,
    èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
62 Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ
    nítorí òfin òdodo rẹ.
63 Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
    sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ.
64 Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ Olúwa
    Kọ́ mi ní òfin rẹ.

Òwe 25:11-22

11 Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ
    ó dàbí èso wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.
12 Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára
    ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.

13 Bí títutù òjò yìnyín ní àsìkò ìkórè
    ni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn tí ó rán an
    ó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú.
14 Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láìsí òjò
    ni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni.

15 Nípa sùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà
    ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.

16 Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nba
    bí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í.
17 Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbo
    tàbí kí ó máa lọ síbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ.

18 Bí ọ̀pá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó mú
    ni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.

19 Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹsẹ̀ tí ó rọ
    ni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdààmú.
20 Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú,
    tàbí, bí ọtí kíkan tí a dà sí ojú ọgbẹ́,
    ní ẹni tí ń kọ orin fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́.

21 (A)Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ;
    bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú.
22 Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí
    Olúwa yóò sì san ọ ní ẹ̀san rẹ̀ fún ọ.

Romu 12:9-21

Ẹ̀kọ́ nípa ìfẹ́

Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn. Ẹ máa takété sí ohun tí í ṣe búburú; ẹ fi ara mọ́ ohun tí í ṣe rere. 10 Ní ti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín; ní ti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú. 11 Ní ti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa. 12 (A)Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gbọingbọin nínú àdúrà. 13 Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò ṣíṣe.

14 (B)Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè. 15 Àwọn tí ń yọ̀, ẹ máa bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkún, ẹ máa bá wọn sọkún. 16 (C)Ẹ máa wà ní inú kan náà sí ara yín. Ẹ má ṣe gbéraga, ṣùgbọ́n ẹ má tẹ̀lé àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín.

17 (D)Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn. 18 (E)Bí ó bá sé é ṣe, bí ó ti wà ní ipa tiyín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. 19 (F)Olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú Ọlọ́run; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, “Tèmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san.” 20 (G)Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀,

“Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ;
    bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.
Ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí.”

21 Má ṣe jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.