Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
96 (A)Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:
Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.
2 Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀
ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́
3 Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.
4 Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;
òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ
5 Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè
ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run
6 Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀
agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.
7 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn
Ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa
8 Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;
ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀
9 Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;
ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.
10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba”
a fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;
ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.
11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo
jẹ́ kí pápá Òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun
gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.
12 Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀
àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀:
nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀
13 Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,
nítorí tí ó ń bọ̀ wá,
Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé
yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé
àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.
Ahabu Jọba lórí Israẹli
29 Ní ọdún kejì-dínlógójì Asa ọba Juda, Ahabu ọmọ Omri jẹ ọba ní Israẹli, o si jẹ ọba lórí Israẹli ní Samaria ní ọdún méjìlélógún. 30 Ahabu ọmọ Omri sì ṣe búburú ní ojú Olúwa ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀ lọ. 31 Ó sì ṣe bí ẹni pé ó ṣe ohun kékeré fún un láti máa rìn nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, ó sì mú Jesebeli, ọmọbìnrin Etibaali, ọba àwọn ará Sidoni ní aya, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ń sin Baali, ó sì bọ ọ́. 32 Ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Baali nínú ilé Baali tí ó kọ́ sí Samaria. 33 Ahabu sì túnṣe ère òrìṣà Aṣerah, ó sì ṣe púpọ̀ láti mú Olúwa Ọlọ́run Israẹli bínú ju èyí tí gbogbo ọba Israẹli tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ ti ṣe lọ.
34 (A)Ní ìgbà ayé Ahabu, Hieli ará Beteli kọ́ Jeriko. Ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀ ní Abiramu, àkọ́bí rẹ, ó sì gbé àwọn ìlẹ̀kùn ibodè rẹ̀ kọ́ ní Segubu àbíkẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti ipa Joṣua ọmọ Nuni sọ.
Paulu àti àwọn aposteli ẹlẹ́kọ̀ọ́ èké
11 (A)Mo rò wí pé ẹ ó faradà díẹ̀ nínú ìwà òmùgọ̀ mi ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ ni, mo fẹ́ kí ẹ gbà mí láàyè. 2 (B)Nítorí pé èmi ń jowú lórí i yín bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run: nítorí tí mo ti fì yín fún ọkọ kan, kí èmi bà á lè mú yín wá bí wúńdíá tí ó mọ́ sọ́dọ̀ Kristi. 3 (C)Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi. 4 (D)Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jesu mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìhìnrere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.
5 (E)Nítorí mo rò pé èmi kò rẹ̀yìn nínú ohunkóhun sí àwọn àgbà Aposteli. 6 (F)Bí mo tilẹ̀ jẹ́ òpè nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kì í ṣe nínú ìmọ̀; Ní ọ̀nàkọnà ni àwa ti fi èyí hàn dájúdájú fún yín nínú ohun gbogbo.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.