Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 46

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. b Orin.

46 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa
    ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.
Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,
    tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.
Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì
    tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.

Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,
    ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.
Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:
    Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.
Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,
    ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.

Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,
    Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.

Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa
    irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.
O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé
    ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì
ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná
10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.
A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè
    A ó gbé mi ga ní ayé.

11 Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa
    Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.

Gẹnẹsisi 2:4-25

Adamu àti Efa

Èyí ni ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọ̀run àti ayé nígbà tí ó dá wọn. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run dá ayé àti àwọn ọ̀run.

Kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí Olúwa Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀. Ṣùgbọ́n ìsun omi ń jáde láti ilẹ̀, ó sì ń bu omi rin gbogbo ilẹ̀. (A)Olúwa Ọlọ́run sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn, ó si mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, ènìyàn sì di alààyè ọkàn.

Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí. (B)Olúwa Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀: àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà.

10 Odò kan sì ń ti Edeni sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin. 11 Orúkọ èkínní ni Pisoni: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà. 12 (Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá (bedeliumu) àti òkúta (óníkìsì) oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú). 13 Orúkọ odò kejì ni Gihoni: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. 14 Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi: òun ni ó sàn ní apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Asiria. Odò kẹrin ni Eufurate.

15 Olúwa Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Edeni láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀. 16 Olúwa Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé, “Ìwọ lè jẹ lára èyíkéyìí èso àwọn igi inú ọgbà; 17 ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti èso igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kùú.”

18 Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.”

19 Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́. 20 Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ.

Ṣùgbọ́n fún Adamu ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀. 21 Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà. 22 Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá.

23 Ọkùnrin náà sì wí pé,

“Èyí ni egungun láti inú egungun mi
    àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi;
‘obìnrin’ ni a ó máa pè é,
    nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.”

24 (C)Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.

25 Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòhò, ojú kò sì tì wọ́n.

Romu 9:6-13

(A)Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá í ṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Israẹli wá, àwọn ni Israẹli: (B)Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn ni ọmọ: Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.” (C)Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú-ọmọ. (D)Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Ní ìwòyí àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sara yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”

10 (E)Kì í sì í ṣe kìkì èyí; Ṣùgbọ́n nígbà tí Rebeka pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Isaaki baba wa. 11 Nítorí nígbà tí kò tí ì bí àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú—kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró, 12 (F)kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kò ṣe ti ẹni tí ń peni—a ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.” 13 (G)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Jakọbu ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Esau ni mo kórìíra.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.