Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi.
5 Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa,
kíyèsi àròyé mi.
2 Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,
ọba mi àti Ọlọ́run mi,
nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.
3 Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;
ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀
èmi yóò sì dúró ní ìrètí.
4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú;
bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.
5 Àwọn agbéraga kò le è dúró
níwájú rẹ̀.
Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;
6 ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run.
Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn
ni Olúwa yóò kórìíra.
7 Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀,
èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀;
ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba
sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.
8 Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ,
nítorí àwọn ọ̀tá mi,
mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.
23 Àwọn ìránṣẹ́ ọba Aramu sì wí fún un pé, “Ọlọ́run wọn, ọlọ́run òkè ni. Ìdí nìyìí tí wọ́n ṣe ní agbára jù wá lọ. Ṣùgbọ́n bí a bá bá wọn jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ dájúdájú. 24 Nǹkan yìí ni kí o sì ṣe: Mú àwọn ọba kúrò, olúkúlùkù kúrò ní ipò rẹ̀, kí o sì fi baálẹ̀ sí ipò wọn. 25 Kí o sì tún kó ogun jọ fún ara rẹ bí èyí tí ó ti sọnù; ẹṣin fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ fún kẹ̀kẹ́; kí a bá lè bá Israẹli jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Nítòótọ́ àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ.” Ó sì gba tiwọn, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.
26 Ó sì ṣe ní àmọ́dún, Beni-Hadadi ka iye àwọn ará Aramu, ó sì gòkè lọ sí Afeki, láti bá Israẹli jagun. 27 Nígbà tí a sì ka àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì pèsè oúnjẹ, wọ́n sì lọ pàdé wọn. Àwọn ọmọ Israẹli sì dó ní òdìkejì wọn gẹ́gẹ́ bí agbo ọmọ ewúrẹ́ kékeré méjì, nígbà tí àwọn ará Aramu kún ilẹ̀ náà.
28 Ènìyàn Ọlọ́run kan sì gòkè wá, ó sì sọ fún ọba Israẹli pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Nítorí tí àwọn ará Aramu rò pé Olúwa, Ọlọ́run òkè ni, ṣùgbọ́n òun kì í ṣe Ọlọ́run Àfonífojì, nítorí náà èmi ó fi gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yìí lé ọ lọ́wọ́, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”
29 Wọ́n sì dó sí òdìkejì ara wọn fún ọjọ́ méje, àti ní ọjọ́ keje, wọ́n pàdé ogun. Àwọn ọmọ Israẹli sì pa ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú àwọn ará Aramu ní ọjọ́ kan. 30 Àwọn tókù sì sá àsálà lọ sí Afeki, sínú ìlú tí odi ti wó lù ẹgbàá-mẹ́tàlá-lé ẹgbẹ̀rún (27,000) nínú wọn. Beni-Hadadi sì sálọ sínú ìlú, ó sì fi ara pamọ́ sínú ìyẹ̀wù.
31 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, a ti gbọ́ pé àwọn ọba ilẹ̀ Israẹli jẹ́ ọba aláàánú, mo bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí àwa kí ó tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ wa, àti okùn yí orí wa ká. Bóyá òun yóò gba ẹ̀mí rẹ là.”
32 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ wọn, Wọ́n sì fi okùn yí orí wọn ká, wọ́n sì tọ ọba Israẹli wá, wọ́n sì wí pé, “ìránṣẹ́ rẹ Beni-Hadadi wí pé, ‘Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí èmi kí ó yè.’ ”
Ọba sì dáhùn wí pé, “Ó ń bẹ láààyè bí? Arákùnrin mi ni òun.”
33 Àwọn ọkùnrin náà sì ṣe àkíyèsí gidigidi, wọ́n sì yára gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Beni-Hadadi arákùnrin rẹ.”
Ọba sì wí pé, “Ẹ lọ mú u wá.” Nígbà tí Beni-Hadadi jáde tọ̀ ọ́ wá, Ahabu sì mú u gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́.
34 Beni-Hadadi sì wí pé, “Èmi yóò dá àwọn ìlú tí baba mi ti gbà lọ́wọ́ baba rẹ padà, ìwọ sì le la ọ̀nà fún ara rẹ ní Damasku, bí baba mi ti ṣe ní Samaria.”
Ahabu sì wí pé, “Èmi yóò rán ọ lọ pẹ̀lú májẹ̀mú yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ba dá májẹ̀mú, ó sì rán an lọ.
Àwọn Israẹli tó ṣẹ́kù
11 (A)Ǹjẹ́ mo ní: Ọlọ́run ha ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù bí? Kí a má ri. Nítorí Israẹli ni èmi pẹ̀lú, láti inú irú-ọmọ Abrahamu, ni ẹ̀yà Benjamini. 2 (B)Ọlọ́run kò ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù ti ó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Tàbí ẹ̀yin kò mọ bí ìwé mímọ́ ti wí ní ti Elijah? Bí ó ti ń bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún Israẹli, wí pé: 3 “Olúwa, wọ́n ti pa àwọn wòlíì rẹ, wọn sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sì kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi.” 4 (C)Ṣùgbọ́n ìdáhùn wo ni Ọlọ́run fi fún un? “Mo ti ṣẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ènìyàn kù sílẹ̀ fún ara mi, àwọn tí kò tẹ eékún ba fún Baali.” 5 (D)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni, ní àkókò yìí àṣẹ́kù àwọn ènìyàn kan wà nípa ìyànfẹ́ ti oore-ọ̀fẹ́. 6 (E)Bí ó bá sì ṣe pé nípa ti oore-ọ̀fẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti iṣẹ́ mọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́ oore-ọ̀fẹ́ kì yóò jẹ́ oore-ọ̀fẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe pé nípa ti iṣẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti oore-ọ̀fẹ́ mọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, iṣẹ́ kì í ṣe iṣẹ́ mọ́.
7 (F)Kí ha ni? Ohun tí Israẹli ń wá kiri, òun náà ni kò rí; ṣùgbọ́n àwọn ẹni àyànfẹ́ ti rí i, a sì sé àyà àwọn ìyókù le. 8 (G)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Ọlọ́run ti fún wọn ní ẹ̀mí oorun,
àwọn ojú tí kò le ríran
àti àwọn etí tí kò le gbọ́rọ̀,
títí ó fi di òní olónìí yìí.”
9 (H)Dafidi sì wí pé:
“Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìdẹ̀kùn àti tàkúté,
ohun ìkọ̀sẹ̀ àti ẹ̀san fún wọn;
10 Jẹ́ kí ojú wọn ṣókùnkùn, kí wọn kí ó má le ríran,
Kí wọn kí ó sì tẹ ẹ̀yìn wọn ba nígbà gbogbo.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.