Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 43:18-25

18 “Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;
    má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
19 Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!
    Nísinsin yìí ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí?
Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀
    àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
20 Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,
    àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,
nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀
    àti odò nínú ilẹ̀ sísá,
láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
21     àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi
    kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.

22 “Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí,
    ìwọ Jakọbu,
àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítorí mi
    ìwọ Israẹli.
23 Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ sísun,
    tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ.
Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ ìyẹ̀fun
    tàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí.
24 Ìwọ kò tí ì ra kalamusi olóòórùn dídùn fún mi,
    tàbí kí o da ọ̀rá ẹbọ rẹ bò mí.
Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín
    ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedéédéé yín.

25 “Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ
    àwọn àìṣedéédéé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi,
    tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.

Saamu 41

Fún adarí orin. Saamu Dafidi.

41 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:
    Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.
Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:
    yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀
kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀
    yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.

Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;
    wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.
Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé
    “Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”
Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,
    wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;
nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.

Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;
    èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,
wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin
    àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,
kì yóò dìde mọ́.”
(A)Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,
    ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,
tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.

10 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;
    gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.
11 Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,
    nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.
12 Bí ó ṣe tèmi ni
    ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi
ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.

13 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli
    láé àti láéláé.
Àmín àti Àmín.

2 Kọrinti 1:18-22

18 Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run tí jẹ́ olóòtítọ́, ọ̀rọ̀ wa fún yín kí í ṣe bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́. 19 (A)Nítorí pé Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí a tí wàásù rẹ̀ láàrín yín nípasẹ̀ èmí àti Silfanu àti Timotiu, kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nínú rẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ ní. 20 (B)Nítorí tí gbogbo ìlérí Ọlọ́run dí bẹ́ẹ̀ ni nínú Kristi. Nítorí ìdí èyí ní a ṣe ń wí pé “Àmín” nípasẹ̀ rẹ̀ sí ògo Ọlọ́run. 21 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Ọlọ́run ni ó fi ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ pẹ̀lú yín nínú Kristi, Òun ni ó ti fi ààmì òróró yàn wá, 22 ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì wá pẹ̀lú, ó sì tí fi Ẹ̀mí rẹ́ sí wa ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ó ń bọ̀.

Marku 2:1-12

Jesu wo aláàrùn ẹ̀gbà sàn

Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, nígbà tí Jesu tún padà wọ Kapernaumu, òkìkí kàn pé ó ti wà nínú ilé. Láìpẹ́, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ti kún ilé tí ó dé sí tó bẹ́ẹ̀ tí inú ilé àti ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ní ìta kò gba ẹyọ ẹnìkan mọ́, ó sì wàásù ọ̀rọ̀ náà sí wọn. (A)Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé. Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jesu, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jesu wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu. Nígbà tí Jesu sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ òfin tó jókòó níbẹ̀ sọ fún ara wọn pé, “Èéṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? Ó ń sọ̀rọ̀-òdì. Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan?”

Lójúkan náà bí Jesu tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yìn fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín? Èwo ni ó rọrùn jù láti wí fún arọ náà pé: ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ,’ tàbí wí pé, ‘Dìde sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?’ 10 Ṣùgbọ́n kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ji ni.” Ó wí fún ọkùnrin arọ náà pé, 11 “Mo wí fún ọ, dìde, gbé àkéte rẹ kí ó sì máa lọ ilé rẹ.” 12 (B)Lójúkan náà, ọkùnrin náà fò sókè fún ayọ̀. Ó gbé àkéte rẹ̀. Ó sì jáde lọ lójú gbogbo wọn. Èyí sì ya gbogbo wọn lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo wí pé, “Àwa kò rí irú èyí rí!”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.