Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 41

Fún adarí orin. Saamu Dafidi.

41 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:
    Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.
Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:
    yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀
kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀
    yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.

Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;
    wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.
Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé
    “Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”
Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,
    wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;
nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.

Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;
    èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,
wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin
    àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,
kì yóò dìde mọ́.”
(A)Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,
    ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,
tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.

10 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;
    gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.
11 Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,
    nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.
12 Bí ó ṣe tèmi ni
    ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi
ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.

13 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli
    láé àti láéláé.
Àmín àti Àmín.

Isaiah 38:1-8

Àìsàn Hesekiah

38 Ní ọjọ́ náà ni Hesekiah ṣe àìsàn dé ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ohun tí Olúwa wí nìyìí: Palẹ̀ ilé è rẹ mọ́, bí ó ti yẹ nítorí pé ìwọ yóò kú; ìwọ kì yóò dìde àìsàn yìí.”

Hesekiah yí ojú u rẹ̀ sí ara ògiri, ó sì gba àdúrà sí Olúwa, “Rántí, Ìwọ Olúwa, bí mo ti rìn pẹ̀lú òtítọ́ níwájú rẹ, àti bí mo ti fi ọkàn dídúró ṣinṣin ṣe ohun tí ó dára ní ojú ù rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah sì sọkún kíkorò.

Lẹ́yìn náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Isaiah wá pé “Lọ kí o sì sọ fún Hesekiah pé, ‘Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ọlọ́run Dafidi baba rẹ sọ pé: Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ; Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. Èmi yóò sì gba ìwọ àti ìlú yìí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí.

“ ‘Èyí yìí ni ààmì tí Olúwa fún ọ láti fihàn wí pé Olúwa yóò mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ: Èmi yóò mú òjìji oòrùn kí ó padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi sọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Ahasi.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀.

Heberu 12:7-13

Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí: Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í bá wí? Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, ǹjẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ. Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríba fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè? 10 Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o bá ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n òun (tọ́ wa) fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀. 11 Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísinsin yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹyìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.

12 (A)Nítorí náà, ẹ na ọwọ́ tí ó rọ, àti eékún àìlera; 13 (B)“Kí ẹ sì ṣe ipa ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kúkú wò ó sàn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.