Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Saamu Dafidi.
41 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:
Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.
2 Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:
yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀
kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
3 Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀
yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.
4 Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;
wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.
5 Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé
“Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”
6 Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,
wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;
nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.
7 Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;
èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,
8 wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin
àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,
kì yóò dìde mọ́.”
9 (A)Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,
ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,
tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.
10 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;
gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.
11 Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,
nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.
12 Bí ó ṣe tèmi ni
ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi
ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.
13 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli
láé àti láéláé.
Àmín àti Àmín.
12 Olúwa sì farahàn Solomoni ní òru ó sì wí pé:
“Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti yàn ibí yìí fún ara mi gẹ́gẹ́ bí ilé fún ẹbọ.
13 “Nígbà tí mo bá sé ọ̀run kí ó ma bá à sí òjò, tàbí láti pàṣẹ fún eṣú láti jẹ ilẹ̀ náà run tàbí rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín àwọn ènìyàn mi, 14 tí àwọn ènìyàn, tí a fi orúkọ mi pè, tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì rí ojú mi, tí wọ́n sì yí kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn, nígbà náà, èmi yóò gbọ́ láti ọ̀run, èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n èmi yóò sì wo ilẹ̀ wọn sàn. 15 Nísinsin yìí, ojú mi yóò sì là etí mi yóò sì là, sí àdúrà ọrẹ níbí yìí. 16 Èmi sì ti yàn, èmi sì ti ya ilé yìí sí mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kí orúkọ mi kí ó le wà níbẹ̀ títí láéláé.
17 “Ní ti bí ìwọ bá rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, tí o sì ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ, tí ìwọ sì ṣe àkíyèsí àṣẹ mi láti ọ̀run: 18 Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe pẹ̀lú Dafidi baba rẹ nígbà tí mo bá a dá májẹ̀mú wí pé, ìwọ kò ní fẹ́ ẹnìkan kù láti ṣe alákòóso lórí Israẹli.
19 “Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá yípadà tí o sì kọ òfin mi sílẹ̀ àti àṣẹ tí mo ti fi fún yín tí ẹ sì lọ sókè láti lọ sin ọlọ́run mìíràn tí ẹ sì bọ wọ́n, 20 Nígbà náà ni èmi yóò fa Israẹli tu kúrò láti ilẹ̀ mi, èyí tí èmi ti fi fún wọn, èmi yóò sì kọ̀ ilé náà sílẹ̀ èyí tí èmi ti yà sọ́tọ̀ fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ṣe ọ̀rọ̀ òwe, n ó fi ṣe ẹlẹ́yà láàrín gbogbo ènìyàn, 21 Àti ní gbogbo àyíká ilé yìí nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni yóò di ohun ìtànjẹ; gbogbo àwọn tí ó bá sì kọjá níbẹ̀ ni yóò jáláyà, wọn yóò sì wí pé, ‘Kí ni ó dé tí Olúwa fì ṣe irú èyí sí ilẹ̀ yí àti sí ilé yìí?’ 22 Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa sílẹ̀, Ọlọ́run baba wọn ẹni tí ó mú wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n sì ti fi ọwọ́ gba ọlọ́run mìíràn mọ́ra, wọ́n bọ wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyí tí ó fi mú gbogbo ìjàǹbá náà wá sórí wọn.’ ”
2 Olùfẹ́, èmi ń gbàdúrà pé nínú ohun gbogbo kí o lè máa dára fún ọ, kí o sì máa wà ni ìlera, àní bí o tí dára fún ọkàn rẹ. 3 Nítorí mo yọ̀ gidigidi, nígbà tí àwọn arákùnrin dé tí wọn sì jẹ́rìí sí ìwà òtítọ́ inú rẹ̀, àní bí ìwọ tí ń rìn nínú òtítọ́. 4 Èmi ni ayọ̀ tí ó tayọ, láti máa gbọ́ pé, àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.
5 Olùfẹ́, ìwọ ń ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún àwọn tí ń ṣe ará, àti pàápàá fún àwọn tí ń ṣe àlejò. 6 Tí wọn ń jẹ́rìí sí ìfẹ́ rẹ̀ níwájú ìjọ: bí ìwọ bá ń pèsè fún wọn ní ọ̀nà àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó tí yẹ nínú Ọlọ́run. 7 Nítorí pé, nítorí iṣẹ́ Kristi ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgba ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn aláìkọlà. 8 Nítorí náà, ó yẹ kí àwa fi inú rere gba irú àwọn wọ̀nyí, kí àwa lè jẹ́ alábáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.