Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin olókùn. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.
6 Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ
kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ
2 Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ;
Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.
3 Ọkàn mi wà nínú ìrora.
Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?
4 Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí;
gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.
5 Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú.
Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú?
6 Agara ìkérora mi dá mi tán.
Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún,
mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
7 Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́;
wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.
8 (A)Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,
nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.
9 Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú;
Olúwa ti gba àdúrà mi.
10 Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú;
wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.
Ussiah ọba Juda
26 (A)Nígbà náà gbogbo ènìyàn Juda mú Ussiah, ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìn-dínlógún wọ́n sì fi jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀ Amasiah. 2 Òun ni ẹni náà tí ó tún Elati kọ́, ó sì mú padà sí Juda lẹ́yìn ìgbà tí Amasiah ọba ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀.
3 Ussiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìn-dínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìléláadọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekoliah; ó sì wá láti Jerusalẹmu. 4 Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bi baba rẹ̀ Amasiah ti ṣe. 5 Ó sì wá Olúwa ní ọjọ́ Sekariah, ẹni tí ó ní òye nínú ìran Ọlọ́run. Níwọ́n ọjọ́ tí ó wá ojú Olúwa, Ọlọ́run fún un ní ohun rere.
6 Ó sì lọ sí ogun pẹ̀lú Filistini ó sì wó odi Gati lulẹ̀, Jabne àti Aṣdodu. Ó sì kó ìlú rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ Aṣdodu àti níbìkan láàrín àwọn ará Filistini. 7 Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lórí àwọn ará Filistini àti Arabia tí ń gbé ní Gur-baali àti lórí àwọn ará Mehuni. 8 Àwọn ará Ammoni gbé ẹ̀bùn wá fún Ussiah, orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri títí ó fi dé àtiwọ Ejibiti, nítorí ó ti di alágbára ńlá.
9 Ussiah sì kọ́ ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi ẹnu-bodè igun, àti níbi ẹnu-bodè Àfonífojì àti níbi ìṣẹ́po odi ó sì mú wọn le 10 Ó sì tún ilé ìṣọ́ aginjù kọ́, ó sì gbẹ́ kànga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ ìsàlẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbà àjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe.
11 Ussiah sì ní àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n kọ́ dáradára, wọ́n múra tán láti lọ pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye kíkà wọn gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ Jeieli akọ̀wé àti Maaseiah ìjòyè lábẹ́ ọwọ́ Hananiah, ọ̀kan lára àwọn olórí ogun ọba. 12 Àpapọ̀ iye olórí àwọn alágbára akọni ogun jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá (2,600). 13 Lábẹ́ olórí àti olùdarí wọn, wọ́n sì jẹ́ alágbára akọni ogun ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (307,500), tí ó ti múra fún ogun ńlá náà, àti alágbára ńlá jagunjagun kan láti ran ọba lọ́wọ́ sí ọ̀tá rẹ̀. 14 Ussiah sì pèsè ọ̀kọ̀, asà, akọ́rọ́, àti ohun èlò ìhámọ́ra ọrun títí dé òkúta kànnàkànnà fún ọwọ́ àwọn ọmọ-ogun. 15 Ní Jerusalẹmu ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun, iṣẹ́ ọwọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn, láti wà lórí ilé ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára.
16 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí Ussiah jẹ́ alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ sì gbé e ṣubú. Ó sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì wọ ilé Olúwa láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí. 17 Asariah àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọgọ́rin alágbára àlùfáà Olúwa mìíràn sì tẹ̀lé e. 18 Wọ́n sì takò ọba Ussiah, wọn sì wí pé, “Kò dára fún ọ, Ussiah, láti sun tùràrí sí Olúwa. Èyí fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Aaroni, ẹni tí ó ti yà sí mímọ́ láti sun tùràrí. Fi ibi mímọ́ sílẹ̀, nítorí tí ìwọ ti jẹ́ aláìṣòótọ́, ìwọ kò sì ní jẹ́ ẹni ọlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run.”
19 Ussiah, ẹni tí ó ní àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀ tó ṣetán láti sun tùràrí sì bínú. Nígbà tí ó sì ń bínú sí àwọn àlùfáà níwájú wọn, níwájú pẹpẹ tùràrí ní ilé Olúwa, ẹ̀tẹ̀ sì yọ jáde ní iwájú orí rẹ̀. 20 (B)Nígbà tí Asariah olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn àlùfáà yòókù sì wò ó, wọ́n sì rí i wí pé ó ní ẹ̀tẹ̀ níwájú orí rẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì sáré gbé e jáde pẹ̀lúpẹ̀lú, òun tìkára rẹ̀ ti fẹ́ láti jáde, nítorí tí Olúwa ti kọlù ú.
21 Ọba Ussiah sì ní ẹ̀tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó sì gbé ní ilé àwọn adẹ́tẹ̀, a sì ké e kúrò ní ilé Olúwa. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.
Peteru mú oníbárà arọ láradà
3 Ní ọjọ́ kan Peteru àti Johanu jùmọ̀ ń gòkè lọ sí tẹmpili ní wákàtí àdúrà; tí í ṣe wákàtí mẹ́ta ọ̀sán. 2 Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹmpili lọ, 3 Nígbà tí ó rí Peteru àti Johanu bí wọn tí fẹ́ wọ inú tẹmpili, ó ṣagbe. 4 Peteru sì tẹjúmọ́ ọn, pẹ̀lú Johanu, ó ní “Wò wá!” 5 Ó sì fiyèsí wọn, ó ń retí láti rí nǹkan láti gbà lọ́wọ́ wọn.
6 Peteru wí pé, “Wúrà àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fi fún ọ: Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, dìde kí o sì máa rìn.” 7 Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde; lójúkan náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun. 8 Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹmpili lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run. 9 Gbogbo ènìyàn sì rí i, ó ń rìn, ó sì yin Ọlọ́run: 10 Wọn sì mọ̀ pé òun ni ó ti jókòó tí ń ṣagbe ní ẹnu-ọ̀nà Dáradára ti tẹmpili náà; hà, sì ṣe wọn, ẹnu sì yà wọn gidigidi sí ohun tí ó ṣe lára rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.